OLUWA wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ ti pọ̀jù fún mi, láti fi àwọn ará ilẹ̀ Midiani lé lọ́wọ́, kí àwọn ọmọ Israẹli má baà gbéraga pé agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun, wọn kò sì ní fi ògo fún mi. Nítorí náà, kéde fún gbogbo wọn pé, kí ẹnikẹ́ni tí ẹ̀rù bá ń bà pada sí ilé.” Gideoni bá dán wọn wò lóòótọ́, ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaa (22,000) ọkunrin ninu wọn sì pada sí ilé. Àwọn tí wọ́n kù jẹ́ ẹgbaarun (10,000).
Kà ÀWỌN ADÁJỌ́ 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÀWỌN ADÁJỌ́ 7:2-3
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò