ÀWỌN ADÁJỌ́ 2:6-23

ÀWỌN ADÁJỌ́ 2:6-23 YCE

Nígbà tí Joṣua tú àwọn ọmọ Israẹli ká, olukuluku wọn pada lọ sí orí ilẹ̀ wọn, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Àwọn eniyan náà sin OLUWA ní gbogbo àkókò tí Joṣua ati àwọn àgbààgbà tí wọ́n kù lẹ́yìn rẹ̀ wà láàyè, àwọn tí wọ́n fi ojú rí àwọn iṣẹ́ ńlá tí OLUWA ṣe fún Israẹli. Joṣua, ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA, ṣaláìsí nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún. Wọ́n sì sin ín sórí ilẹ̀ rẹ̀ ní Timnati Sera, ní agbègbè olókè ti Efuraimu ní ìhà àríwá òkè Gaaṣi. Gbogbo ìṣọ̀wọ́ àwọn tí wọ́n mọ OLUWA ati ohun tí ó ti ṣe fún Israẹli patapata ni wọ́n kú, àwọn ìran mìíràn sì dìde lẹ́yìn wọn, wọn kò mọ OLUWA, ati gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n ń bọ oriṣa Baali. Wọ́n kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn tí ó kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀, wọ́n ń bọ lára àwọn oriṣa àwọn tí wọ́n yí wọn ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n sì mú inú bí OLUWA. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọ́n ń bọ oriṣa Baali ati Aṣitarotu. Inú bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, ó bá fi wọ́n lé àwọn jàǹdùkú ọlọ́ṣà kan lọ́wọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jí wọn ní nǹkan kó. OLUWA tún fi wọ́n lé gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó wà ní àyíká wọn lọ́wọ́, apá wọn kò sì ká àwọn ọ̀tá wọn mọ́. Nígbàkúùgbà tí wọ́n bá jáde lọ láti jagun, OLUWA á kẹ̀yìn sí wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti kìlọ̀ fún wọn tí ó sì búra fún wọn, ìdààmú a sì dé bá wọn. Lẹ́yìn náà, OLUWA á gbé àwọn adájọ́ kan dìde, àwọn adájọ́ náà á sì gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú ọlọ́ṣà tí ń kó wọn ní nǹkan. Sibẹsibẹ, wọn kì í gbọ́ ti àwọn aṣiwaju wọn. Wọn a máa sá lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa káàkiri, wọn a sì máa bọ wọ́n. Láìpẹ́ láìjìnnà, wọ́n á yipada kúrò ní ọ̀nà tí àwọn baba wọn ń rìn. Àwọn baba wọn a máa pa òfin OLUWA mọ́, ṣugbọn ní tiwọn àwọn kì í pa á mọ́. Nígbàkúùgbà tí OLUWA bá gbé aṣiwaju kan dìde fún wọn, OLUWA a máa wà pẹlu aṣiwaju náà, a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn, ní àkókò aṣiwaju náà. Ìkérora àwọn ọmọ Israẹli a máa mú kí àánú wọn ṣe OLUWA, nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá ń fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n sì ń ni wọ́n lára. Ṣugbọn bí aṣiwaju yìí bá ti kú, kíá, wọn a tún ti yipada, wọn a sì tún ti máa ṣe ohun tí ó burú ju ohun tí àwọn baba wọn ti ṣe lọ. Wọn a máa lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa, wọ́n a máa bọ wọ́n, wọn a sì máa foríbalẹ̀ fún wọn. Wọn kì í sì í fi ìṣe wọn ati oríkunkun wọn sílẹ̀. Nítorí náà inú a bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, a sì wí pé, “Àwọn eniyan wọnyi ti da majẹmu tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba wọn, wọn kò sì fetí sí òfin mi. Láti ìsinsìnyìí lọ n kò ní lé èyíkéyìí, ninu àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù kí Joṣua tó kú, jáde fún wọn. Àwọn ni n óo lò láti wò ó bí àwọn ọmọ Israẹli yóo máa tọ ọ̀nà tí mo là sílẹ̀, bí àwọn baba ńlá wọn ti ṣe.” Nítorí náà, OLUWA fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀ náà, kò tètè lé wọn jáde bí kò ti fún Joṣua lágbára láti ṣẹgun wọn.