Tí a bá fi ìjánu sí ẹṣin lẹ́nu, kí wọ́n lè ṣe bí a ti fẹ́, a máa darí gbogbo ara wọn bí a bá ti fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo àwọn ọkọ̀ ojú omi. Bí wọ́n ti tóbi tó, tí ó jẹ́ pé afẹ́fẹ́ líle ní ń gbé wọn kiri, sibẹ ìtukọ̀ kékeré ni ọ̀gá àwọn atukọ̀ fi ń darí wọn sí ibi tí ó bá fẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n, ẹ̀yà ara kékeré ni, ṣugbọn ìhàlẹ̀ rẹ̀ pọ̀. Ẹ wo bírà tí iná kékeré lè dá ninu igbó ńlá! Iná ni ahọ́n. Ó kún fún àwọn nǹkan burúkú ayé yìí. Ninu àwọn ẹ̀yà ara wa, ahọ́n ni ó ń kó nǹkan ibi bá gbogbo ara. A máa mú kí gbogbo ara wá gbóná, iná ọ̀run àpáàdì ni ó túbọ̀ ń fún un ní agbára. Gbogbo ẹ̀dá pátá: ati ẹranko ni, ati ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà, ati àwọn ẹran omi, gbogbo wọn ni eniyan lè so lójú rọ̀. Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó kápá ahọ́n. Nǹkan burúkú tí ó kanpá ni, ó kún fún oró tí ó lè paniyan kíákíá. Ahọ́n ni a fi ń yin Oluwa ati Baba. Òun kan náà ni a fi ń ṣépè fún eniyan tí a dá ní àwòrán Ọlọrun. Láti inú ẹnu kan náà ni ìyìn ati èpè ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, kò yẹ kí èyí rí bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ omi dídùn ati omi kíkorò lè ti inú orísun omi kan náà jáde?
Kà JAKỌBU 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JAKỌBU 3:3-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò