Nígbà ayé Ahasi, ọmọ Jotamu, ọmọ Usaya, ọba Juda, Resini Ọba Siria ati Peka ọmọ Remalaya, ọba Israẹli wá gbé ogun ti Jerusalẹmu, ṣugbọn wọn kò lè ṣẹgun rẹ̀. Nígbà tí ìròyìn dé ilé ọba Dafidi pé àwọn ará Siria ati Efuraimu ń gbógun bọ̀, ọkàn òun ati àwọn eniyan rẹ̀ mì tìtì bí afẹ́fẹ́ tíí mi igi ninu igbó.
OLUWA sọ fún Aisaya pé, “Lọ bá Ahasi, ìwọ ati Ṣeari Jaṣubu, ọmọ rẹ, ní òpin ibi tí wọ́n fa omi dé ní ọ̀nà àwọn alágbàfọ̀. Kí o sọ fún un pé, ṣọ́ra, farabalẹ̀, má sì bẹ̀rù. Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ já rárá nítorí ibinu gbígbóná Resini ati Siria, ati ti ọmọ Remalaya, nítorí wọn kò yàtọ̀ sí àjókù igi iná meji tí ń rú èéfín. Nítorí pé Siria, pẹlu Efuraimu ati ọmọ Remalaya ti pète ati ṣe ọ́ ní ibi. Wọ́n ń sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ gbógun ti Juda, kí á dẹ́rùbà á, ẹ jẹ́ kí á ṣẹgun rẹ̀ kí á sì gbà á, kí á fi ọmọ Tabeeli jọba lórí rẹ̀!’
“Àbá tí wọn ń dá kò ní ṣẹ, ète tí wọn ń pa kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ṣebí Damasku ni olú-ìlú Siria, Resini sì ni olórí Damasku. Láàrin ìsinyìí sí ọdún marundinlaadọrin, Efuraimu yóo fọ́nká, kò sì ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́. Ṣebí Samaria ni olú-ìlú Efuraimu, Ọmọ Remalaya sì ni olórí Samaria. Bí ẹ kò bá gbàgbọ́ ẹ kò ní fẹsẹ̀ múlẹ̀.”
OLUWA tún sọ fún Ahasi pé: “Bèèrè àmì tí ó bá wù ọ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun rẹ–ìbáà jìn bí isà òkú, tabi kí ó ga bí ojú ọ̀run.” Ṣugbọn Ahasi dáhùn, ó ní: “Èmi kò ní bèèrè nǹkankan, n kò ní dán OLUWA wò.” Aisaya bá dáhùn pé, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Dafidi, ṣé eniyan tí ẹ̀ ń yọ lẹ́nu kò to yín, Ọlọrun mi alára lókù tí ẹ tún ń yọ lẹ́nu? Nítorí náà, OLUWA fúnrarẹ̀ yóo fun yín ní àmì kan. Ẹ gbọ́! Ọlọ́mọge kan yóo lóyún yóo sì bí ọmọkunrin kan, yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli. Nígbà tí yóo bá fi mọ bí a ti í kọ nǹkan burúkú, tí a sì í yan nǹkan rere, wàrà ati oyin ni àwọn eniyan yóo máa jẹ. Nítorí pé kí ọmọ náà tó mọ bí a ti í kọ nǹkan burúkú tí a sì í yan nǹkan rere, ilẹ̀ àwọn ọba mejeeji tí wọn ń bà ọ́ lẹ́rù yìí yóo ti di ìkọ̀sílẹ̀.
“OLUWA yóo mú ọjọ́ burúkú dé bá ìwọ ati àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ, ọjọ́ tí kò ì tíì sí irú rẹ̀ rí, láti ìgbà tí Efuraimu ti ya kúrò lára Juda, OLUWA ń mú ọba Asiria bọ̀.