AISAYA 66:1-2

AISAYA 66:1-2 YCE

OLUWA ní: “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi. Ilé tí ẹ kọ́ fún mi dà? Níbo sì ni ibi ìsinmi mi wà? Ọwọ́ mi ni mo fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi, tèmi sì ni gbogbo wọn. Ẹni tí n óo kà kún, ni onírẹ̀lẹ̀ ati oníròbìnújẹ́ eniyan, tí ó ń wárìrì nítorí ọ̀rọ̀ mi.