OLUWA ní, “Ẹ la ọ̀nà, ẹ la ọ̀nà, ẹ tún ọ̀nà ṣe, ẹ mú gbogbo ohun ìkọsẹ̀ kúrò lọ́nà àwọn eniyan mi.” Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ, ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́: òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́, ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀. Láti sọ ọkàn wọn jí. Nítorí n kò ní máa jà títí ayé, tabi kí n máa bínú nígbà gbogbo: nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni ẹ̀mí ti ń jáde, Èmi ni mo dá èémí ìyè. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ojúkòkòrò rẹ̀, inú bí mi, mo jẹ ẹ́ níyà, mo fojú pamọ́, inú sì bí mi; sibẹ ó túbọ̀ ń ṣìnà sí i ni, ó ń ṣe tinú rẹ̀. Mo ti rí bí ó ti ń ṣe, ṣugbọn n óo ṣì wò ó sàn; n óo máa darí rẹ̀, n óo tù ú ninu, n óo sì fún àwọn tí ó bá ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli ní orin ayọ̀. Alaafia ni, alaafia ni fún àwọn tí ó wà ní òkèèrè, ati àwọn tí ó wà nítòsí; n óo sì wò wọ́n sàn. Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú dàbí ríru omi òkun, nítorí òkun kò lè sinmi, omi rẹ̀ a sì máa rú pàǹtí ati ẹrẹ̀ sókè. Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.” Ọlọrun mi ló sọ bẹ́ẹ̀.
Kà AISAYA 57
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: AISAYA 57:14-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò