Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; OLUWA fi ẹ̀sùn kan gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé, “Kò sí òtítọ́, tabi àánú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀ Ọlọrun ní ilẹ̀ náà, àfi ìbúra èké ati irọ́ pípa; ìpànìyàn, olè jíjà ati àgbèrè ni ó pọ̀ láàrin wọn. Wọ́n ń yẹ àdéhùn, wọ́n ń paniyan léraléra. Nítorí náà, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀ ń jìyà, àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn ẹja sì ń ṣègbé.”
Ọlọrun ní, Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jiyàn, ẹ kò sì gbọdọ̀ ka ẹ̀sùn sí ẹnikẹ́ni lẹ́sẹ̀, nítorí pé ẹ̀yin alufaa gan-an ni mò ń fi ẹ̀sùn kàn. Nítorí ẹ óo fẹsẹ̀ kọ lojumọmọ, ẹ̀yin wolii pàápàá yóo kọsẹ̀ lóru, n óo sì pa Israẹli, ìyá yín run. Àwọn eniyan mi ń ṣègbé nítorí àìsí ìmọ̀; nítorí pé ẹ̀yin alufaa ti kọ ìmọ̀ mi sílẹ̀, èmi náà yóo kọ̀ yín ní alufaa mi. Nítorí pé ẹ ti gbàgbé òfin Ọlọrun yín, èmi náà yóo gbàgbé àwọn ọmọ yín.
“Bí ẹ̀yin alufaa ti ń pọ̀ sí i, ni ẹ̀ṣẹ̀ yín náà ń pọ̀ sí i, n óo yí ògo wọn pada sí ìtìjú. Ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi wá oúnjẹ fún ara yín, ẹ sì ń mú kí wọ́n máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ Ìyà kan náà ni ẹ̀yin alufaa ati àwọn eniyan yóo jẹ, n óo jẹ yín níyà nítorí ìwà burúkú yín, n óo sì gbẹ̀san lára yín nítorí ìṣe yín. Ẹ óo máa jẹun, ṣugbọn ẹ kò ní yó; Ẹ óo máa ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ṣugbọn ẹ kò ní pọ̀ sí i; nítorí ẹ ti kọ èmi Ọlọrun sílẹ̀ ẹ sì yipada sí ìwà ìbọkúbọ.”