HEBERU 10:1-18

HEBERU 10:1-18 YCE

Nítorí Òfin Mose jẹ́ òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀, kì í ṣe àwòrán wọn gan-an. Òfin ṣe ìlànà nípa irú ẹbọ kan náà tí àwọn eniyan yóo máa rú lọdọọdun. Ṣugbọn òfin kò lè sọ àwọn tí ń wá siwaju Ọlọrun di pípé. Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ẹbọ yìí ti sọ àwọn tí ń rú wọn di pípé ni, wọn kì bá tí rú wọn mọ́, nítorí ẹ̀rí-ọkàn wọn kì bá tí dá wọn lẹ́bi mọ́ bí ó bá jẹ́ pé ẹbọ tí wọ́n rú lẹ́ẹ̀kan bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́. Ṣugbọn àwọn ẹbọ wọnyi ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí lọdọọdun, nítorí ẹ̀jẹ̀ mààlúù ati ti ewúrẹ́ kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ. Nítorí náà, nígbà tí Kristi wọ inú ayé wá, ó sọ fún Ọlọrun pé, “Kì í ṣe ẹbọ ati ọrẹ ni o fẹ́, ṣugbọn o ti ṣe ètò ara kan fún mi. Kì í ṣe ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni o ní inú dídùn sí. Nígbà náà ni mo sọ pé, ‘Èmi nìyí. Àkọsílẹ̀ wà ninu Ìwé Mímọ́ nípa mi pé, Ọlọrun, mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.’ ” Ní àkọ́kọ́ ó ní, “Kì í ṣe ẹbọ ati ọrẹ tabi ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni o fẹ́, kì í ṣe àwọn ni inú rẹ dùn sí.” Àwọn ẹbọ tí wọn ń rú nìyí gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti Òfin. Lẹ́yìn náà ó wá sọ pé, “Èmi nìyí, mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.” Èyí ni pé ó mú ti àkọ́kọ́ kúrò kí ó lè fi ekeji lélẹ̀. Nípa ìfẹ́ Ọlọrun náà ni a fi yà wá sọ́tọ̀ nítorí ẹbọ tí Jesu fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Àwọn alufaa a máa dúró lojoojumọ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, láti máa rú ẹbọ kan náà tí kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ nígbàkúùgbà. Ṣugbọn òun ṣe ìrúbọ lẹ́ẹ̀kan fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tó fún gbogbo ìgbà, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. Níbẹ̀ ni ó wà tí ó ń retí ìgbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo di àpótí-ìtìsẹ̀ rẹ̀. Nítorí nípa ẹbọ kan ó sọ àwọn tí a yà sọ́tọ̀ di pípé títí lae. Nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà fún wa. Ó kọ́kọ́ sọ báyìí pé, “Èyí ni majẹmu tí n óo bá wọn dá nígbà tí ó bá yá, Èmi Oluwa ni mo sọ bẹ́ẹ̀, Èmi óo fi òfin mi sí ọkàn wọn, n óo kọ wọ́n sí àyà wọn.” Ó tún ní, “N kò ní ranti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú wọn mọ́.” Nígbà tí a bá ti dárí àwọn nǹkan wọnyi ji eniyan, kò tún sí ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.