Adura tí wolii Habakuku kọ lórin nìyí: OLUWA, mo ti gbọ́ òkìkí rẹ, mo sì bẹ̀rù iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Gbogbo bí ò ó tíí ṣe tí à ń gbọ́; tún wá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tiwa; sì ranti àánú ní àkókò ibinu rẹ. OLUWA wá láti Temani, Ẹni Mímọ́ sì wá láti òkè Parani. Ògo rẹ̀ bo ojú ọ̀run, gbogbo ayé sì kún fún ìyìn rẹ̀. Dídán rẹ̀ dàbí ọ̀sán gangan, ìtànṣán ń ti ọwọ́ rẹ̀ jáde; níbẹ̀ ni ó fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí. Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ níwájú rẹ̀, ìyọnu sì ń tẹ̀lé e lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí. Ó dúró, ó wọn ayé; Ó wo ayé, ó sì mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì; àwọn òkè ńláńlá ayérayé túká, àwọn òkè àtayébáyé sì wọlẹ̀. Ọ̀nà àtayébáyé ni ọ̀nà rẹ̀. Mo rí àwọn àgọ́ Kuṣani ninu ìyọnu, àwọn aṣọ ìkélé àwọn ará ilẹ̀ Midiani sì ń mì tìtì. OLUWA, ṣé àwọn odò ni inú rẹ ń ru sí ni, àbí àwọn ìṣàn omi ni ò ń bínú sí, tabi òkun ni ò ń bá bínú, nígbà tí o bá gun àwọn ẹṣin rẹ, tí o wà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ? Ìwọ tí ò ń tu àkọ̀ kúrò lára ọrun, tí o fi ọfà lé ọsán ọrun; tí o wá fi omi pín ilẹ̀ ayé. Nígbà tí àwọn òkè ńlá rí ọ, wọ́n wárìrì; àgbàrá omi wọ́ kọjá; ibú òkun pariwo, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè. Oòrùn ati òṣùpá dúró ní ipò wọn, nígbà tí ọfà rẹ ń já lọ ṣòòrò, tí àwọn ọ̀kọ̀ rẹ náà ń kọ mànà, bí wọ́n ti ń fò lọ. O la ayé kọjá pẹlu ibinu, o sì fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀. O jáde lọ láti gba àwọn eniyan rẹ là, láti gba àwọn àyànfẹ́ rẹ là. O wó orí aṣiwaju ilẹ̀ àwọn ẹni ibi wómúwómú, o tú u sí ìhòòhò láti itan dé ọrùn. O fi ọ̀kọ̀ rẹ gún orí àwọn olórí ogun; àwọn tí wọ́n wá bí ìjì líle láti tú wa ká, tí wọn ń yọ̀ bí ẹni tí ń ni talaka lára níkọ̀kọ̀. O fi àwọn ẹṣin rẹ tẹ òkun mọ́lẹ̀; wọ́n tẹ ríru omi mọ́lẹ̀.
Kà HABAKUKU 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: HABAKUKU 3:1-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò