JẸNẸSISI 6:5-22

JẸNẸSISI 6:5-22 YCE

Nígbà tí OLUWA rí i pé ìwà burúkú eniyan ti pọ̀ jù láyé, ati pé kìkì ibi ni èrò inú wọn nígbà gbogbo, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi pé ó dá eniyan sí ayé, ó sì dùn ún, tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “N óo pa àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo dá run lórí ilẹ̀ ayé, ati eniyan ati ẹranko ati àwọn ohun tí ń fàyà fà káàkiri lórí ilẹ̀, ati ẹyẹ, gbogbo wọn ni n óo parun, nítorí ó bà mí ninu jẹ́ pé mo dá wọn.” Ṣugbọn Noa rí ojurere OLUWA. Ìtàn ìran Noa nìyí: Noa jẹ́ olódodo, òun nìkan ṣoṣo ni eniyan pípé ní àkókò tirẹ̀, ó sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu OLUWA. Ó bí ọmọkunrin mẹta tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti. Ayé kún fún ìwà ìbàjẹ́ lójú Ọlọrun, ìwà jàgídíjàgan sì gba gbogbo ayé. Ọlọrun rí i pé ayé ti bàjẹ́, nítorí pé ìwà ìbàjẹ́ ni gbogbo eniyan ń hù. Ọlọrun bá sọ fún Noa pé, “Mo ti pinnu láti pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, nítorí ìwà ipá wọn ti gba gbogbo ayé, àtàwọn àtayé ni n óo parun. Nítorí náà, fi igi goferi kan ọkọ̀ ojú omi fún ara rẹ. Ṣe ọpọlọpọ yàrá sinu rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà kùn ún ninu ati lóde. Bí o óo ti kan ọkọ̀ náà nìyí: kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọọdunrun (300) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, gíga rẹ̀ yóo jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. Kan òrùlé sí orí ọkọ̀ náà, ṣugbọn fi ààyè sílẹ̀ láàrin orí rẹ̀ ati ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yíká, tí yóo jẹ́ ìwọ̀n igbọnwọ kan. Kí o kan ọkọ̀ náà ní ìpele mẹta, kí o sì ṣe ẹnu ọ̀nà sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. N óo jẹ́ kí ìkún omi bo gbogbo ayé, yóo pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, gbogbo ohun ẹlẹ́mìí tí ó wà láyé ni yóo kú. Ṣugbọn n óo bá ọ dá majẹmu, o óo wọ inú ọkọ̀ náà, ìwọ pẹlu aya rẹ ati àwọn ọmọkunrin rẹ ati àwọn aya wọn. Kí o sì mú meji meji ninu gbogbo ohun alààyè, kí wọ́n lè wà láàyè pẹlu rẹ, takọ-tabo ni kí o mú wọn. Meji meji yóo tọ̀ ọ́ wá ninu oríṣìíríṣìí àwọn ẹyẹ, ati oríṣìíríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn, ati oríṣìíríṣìí àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, kí o lè mú kí wọ́n wà láàyè pẹlu rẹ. Kí o sì kó oniruuru oúnjẹ sinu ọkọ̀ náà fún ara rẹ ati fún wọn.” Noa bá ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun pàṣẹ fún un.