JẸNẸSISI 45:1-8

JẸNẸSISI 45:1-8 YCE

Josẹfu kò lè mú ọ̀rọ̀ yìí mọ́ra mọ́ lójú gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ó bá kígbe, ó ní, “Gbogbo yín patapata, ẹ jáde kúrò lọ́dọ̀ mi.” Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ Josẹfu nígbà tí ó fi ara rẹ̀ han àwọn arakunrin rẹ̀ pé òun ni Josẹfu. Ó bú sẹ́kún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pohùnréré ẹkún tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti ati gbogbo ilé Farao gbọ́ ẹkún rẹ̀. Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé òun ni Josẹfu. Ó bi wọ́n léèrè pé ǹjẹ́ baba òun ṣì wà láàyè. Ṣugbọn jìnnìjìnnì dà bo àwọn arakunrin rẹ̀ níwájú rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lè dáhùn. Josẹfu bá bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ wọ́n, ó ní kí wọ́n jọ̀wọ́, kí wọ́n súnmọ́ òun. Ó tún wí fún wọn pé òun ni Josẹfu arakunrin wọn, tí wọ́n tà sí Ijipti. Ó ní, “Ẹ má wulẹ̀ dààmú ẹ̀mí ara yín, ẹ má sì bínú sí ara yín pé ẹ tà mí síhìn-ín. Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni ó rán mi ṣáájú yín láti gba ẹ̀mí là. Nítorí ó ti di ọdún keji tí ìyàn yìí ti bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ yìí, ó sì ku ọdún marun-un gbáko tí kò fi ní sí ìfúrúgbìn tabi ìkórè. Ọlọrun ni ó rán mi ṣáájú yín láti dá yín sí, ati láti gba ọpọlọpọ ẹ̀mí là ninu ìran yín. Nítorí náà, kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbé mi dé ìhín, Ọlọrun ni, ó sì ti fi mí ṣe baba fún Farao, ati oluwa ninu gbogbo ilé rẹ̀ ati alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ijipti.