Bí wọ́n ti tú àpò wọn, olukuluku bá owó rẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀. Nígbà tí àwọn ati baba wọn rí èyí, àyà wọn já. Jakọbu baba wọn bá sọ fún wọn, ó ní, “Ẹ ti jẹ́ kí n ṣòfò àwọn ọmọ mi: Josẹfu ti kú, Simeoni kò sí mọ́, ẹ tún fẹ́ mú Bẹnjamini lọ. Èmi nìkan ni gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ sí tán!” Reubẹni bá wí fún baba rẹ̀ pé, “Pa àwọn ọmọ mi mejeeji, bí n kò bá mú Bẹnjamini pada wá fún ọ. Fi lé mi lọ́wọ́, n óo sì mú un pada wá fún ọ.” Ṣugbọn Jakọbu dáhùn, ó ní, “Ọmọ tèmi kò ní bá yín lọ, nítorí pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ni ó kù. Bí ohunkohun bá ṣẹlẹ̀ sí i ní ìrìn àjò tí ẹ fẹ́ lọ yìí, mo ti darúgbó, ìbànújẹ́ rẹ̀ ni yóo rán mi sọ́run.”
Kà JẸNẸSISI 42
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JẸNẸSISI 42:35-38
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò