Bí Jakọbu ti gbé ojú sókè, ó rí Esau tí ń bọ̀ pẹlu irinwo (400) ọkunrin. Ó bá pín àwọn ọmọ rẹ̀ fún Lea ati Rakẹli, ati àwọn iranṣẹbinrin mejeeji. Ó ti àwọn iranṣẹbinrin ati àwọn ọmọ wọn ṣáájú, Lea ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì tẹ̀lé wọn, Rakẹli ati Josẹfu ni wọ́n wà lẹ́yìn patapata. Jakọbu alára bá bọ́ siwaju gbogbo wọn, ó wólẹ̀ nígbà meje títí tí ó fi súnmọ́ Esau, arakunrin rẹ̀. Esau sáré pàdé rẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó so mọ́ ọn lọ́rùn, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, àwọn mejeeji sì sọkún. Nígbà tí Esau gbé ojú sókè, tí ó rí àwọn obinrin ati àwọn ọmọ, ó ní, “Ta ni àwọn wọnyi tí wọ́n wà pẹlu rẹ?”
Jakọbu dáhùn, ó ní, “Àwọn ọmọ tí Ọlọrun fi ta èmi iranṣẹ rẹ lọ́rẹ ni.” Àwọn iranṣẹbinrin ati àwọn ọmọ wọn bá súnmọ́ wọn, wọ́n sì wólẹ̀ fún Esau. Lea ati àwọn ọmọ rẹ̀ náà súnmọ́ wọn, àwọn náà wólẹ̀ fún un, lẹ́yìn náà ni Josẹfu ati Rakẹli súnmọ́ ọn, àwọn náà wólẹ̀ fún un bákan náà.
Ó bá bèèrè, ó ní, “Kí ni o ti fẹ́ ṣe gbogbo àwọn agbo ẹran tí mo pàdé lọ́nà?” Jakọbu dáhùn, ó ní, “Mo ní kí n fi wọ́n wá ojurere Esau, oluwa mi ni.”
Ṣugbọn Esau dáhùn pé, “Èyí tí mo ní ti tó mi, arakunrin mi, máa fi tìrẹ sọ́wọ́.”
Ṣugbọn Jakọbu dáhùn pé, “Rárá o, jọ̀wọ́, bí mo bá bá ojurere rẹ pàdé nítòótọ́ gba ẹ̀bùn tí mo mú wá lọ́wọ́ mi, nítorí pé rírí tí mo rí ojú rẹ tí inú rẹ sì yọ́ sí mi tó báyìí, ó dàbí ìgbà tí mo rí ojú Ọlọrun. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn tí mo mú wá fún ọ nítorí pé Ọlọrun ti ṣe oore fún mi lọpọlọpọ ati pé mo ní ànító.” Jakọbu rọ̀ ọ́ títí tí ó fi gbà á.
Lẹ́yìn náà, Esau sọ fún Jakọbu pé, “Jẹ́ kí á múra kí á máa lọ n óo sì ṣáájú.”
Ṣugbọn Jakọbu dá a lóhùn, ó ní, “Ṣebí oluwa mi mọ̀ pé àwọn ọmọ kò lágbára tóbẹ́ẹ̀ ati pé mo níláti ro ti àwọn ẹran tí wọ́n ní ọmọ wẹ́wẹ́ lẹ́yìn, bí a bá dà wọ́n ní ìdàkudà ní ọjọ́ kan péré, gbogbo agbo ni yóo run. Oluwa mi, máa lọ níwájú, n óo máa bọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ níwọ̀n bí ìrìn àwọn ẹran ati àwọn ọmọ bá ti lè yá mọ, títí tí n óo fi wá bá oluwa mi ní Seiri.”
Esau bá ní, “Jẹ́ kí n fi àwọn bíi mélòó kan sílẹ̀ pẹlu rẹ ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi.” Ṣugbọn Jakọbu dá a lóhùn pé, “Mo dúpẹ́, má wulẹ̀ ṣe ìyọnu kankan. Àní, kí n ṣá ti rí ojurere oluwa mi.” Esau bá yipada ní ọjọ́ náà, ó gbọ̀nà Seiri. Ṣugbọn Jakọbu lọ sí Sukotu o kọ́ ilé kan fún ara rẹ̀ ó sì ṣe àtíbàbà fún àwọn ẹran rẹ̀. Nítorí náà ni wọ́n Ṣe ń pe ibẹ̀ ní Sukotu.
Nígbà tí ó yá, Jakọbu dé sí Ṣekemu ní ilẹ̀ Kenaani ní alaafia, nígbà tí ó ń pada ti Padani-aramu bọ̀ ó pàgọ́ rẹ̀ siwaju ìlú náà. Ó ra ilẹ̀ ibi tí ó pàgọ́ rẹ̀ sí ní ọgọrun-un (100) gẹsita lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó sì sọ pẹpẹ náà ní Eli-Ọlọrun-Israẹli.