JẸNẸSISI 27:1-29

JẸNẸSISI 27:1-29 YCE

Nígbà tí Isaaki di arúgbó, tí ojú rẹ̀ sì di bàìbàì tóbẹ́ẹ̀ tí kò le ríran mọ́, ó pe Esau àkọ́bí rẹ̀, ó ní, “Ọmọ mi.” Esau sì dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí.” Isaaki wí pé, “Ṣé o rí i báyìí pé mo ti darúgbó, n kò sì mọ ọjọ́ ikú mi. Kó àwọn ohun ọdẹ rẹ: ọrun ati ọfà rẹ, lọ sí ìgbẹ́, kí o sì pa ẹran wá fún mi. Lẹ́yìn náà, se irú oúnjẹ aládùn tí mo fẹ́ràn fún mi, kí n jẹ ẹ́, kí ọkàn mi lè súre fún ọ kí n tó kú.” Ní gbogbo ìgbà tí Isaaki ń bá Esau ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, Rebeka ń gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ. Nítorí náà nígbà tí Esau jáde lọ sinu ìgbẹ́, Rebeka pe Jakọbu ọmọ rẹ̀, ó sọ fún un, ó ní, “Mo gbọ́ tí baba yín ń bá Esau ẹ̀gbọ́n rẹ sọ̀rọ̀, pé kí ó lọ pa ẹran wá fún òun, kí ó sì se oúnjẹ aládùn kí òun lè jẹ ẹ́, kí òun sì súre fún un níwájú OLUWA kí òun tó kú. Nítorí náà, ọmọ mi, fetí sílẹ̀ kí o sì ṣe ohun tí n óo sọ fún ọ. Lọ sinu agbo ẹran rẹ, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ meji tí ó lọ́ràá wá, kí n fi se irú oúnjẹ aládùn tí baba yín fẹ́ràn fún un, o óo sì lọ gbé e fún baba yín, kí ó jẹ ẹ́, kí ó baà lè súre fún ọ, kí ó tó kú.” Ṣugbọn Jakọbu dá Rebeka ìyá rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Onírun lára ni Esau, ẹ̀gbọ́n mi, n kò sì ní irun lára. Ó ṣeéṣe kí baba mi fi ọwọ́ pa mí lára, yóo wá dàbí ẹni pé mo wá fi ṣe ẹlẹ́yà. Nípa bẹ́ẹ̀ n óo fa ègún sórí ara mi dípò ìre.” Ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Kí ègún náà wá sí orí mi, ọmọ mi, ṣá gba ohun tí mo wí, kí o sì lọ mú àwọn ewúrẹ́ náà wá.” Jakọbu bá lọ mú wọn wá fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì se irú oúnjẹ aládùn tí baba wọn fẹ́ràn. Lẹ́yìn náà Rebeka mú aṣọ Esau, àkọ́bí rẹ̀, tí ó dára jùlọ, tí ó wà nílé lọ́dọ̀ rẹ̀, ó wọ̀ ọ́ fún Jakọbu ọmọ rẹ̀. Ó mú awọ ewúrẹ́ tí ó pa, ó fi bo ọwọ́ Jakọbu ati ibi tí ó ń dán ní ọrùn rẹ̀, ó sì gbé oúnjẹ aládùn tí ó sè ati àkàrà tí ó tọ́jú fún Jakọbu ọmọ rẹ̀. Ni Jakọbu bá tọ baba rẹ̀ lọ, ó pè é, ó ní, “Baba mi,” Baba rẹ̀ bá dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi, ìwọ ta ni?” Jakọbu dá baba rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni, mo ti ṣe bí o ti wí, dìde jókòó, kí o sì jẹ ninu ẹran ìgbẹ́ tí mo pa, kí o lè súre fún mi.” Ṣugbọn Isaaki bi í léèrè pé, “O ti ṣe é tí o fi rí ẹran pa kíákíá bẹ́ẹ̀ ọmọ mi?” Jakọbu dáhùn pé “OLUWA Ọlọrun rẹ ni ó ṣe ọ̀nà mi ní rere.” Isaaki bá wí tìfura-tìfura pé, “Súnmọ́ mi, kí n fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Esau ọmọ mi ni ọ́ lóòótọ́.” Jakọbu bá súnmọ́ Isaaki baba rẹ̀, baba rẹ̀ fọwọ́ pa á lára, ó wí pé, “Ọwọ́ Esau ni ọwọ́ yìí, ṣugbọn ohùn Jakọbu ni ohùn yìí.” Kò sì dá Jakọbu mọ̀, nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ ní irun bíi ti Esau ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó bá súre fún un. Ó bèèrè pé, “Ṣé ìwọ gan-an ni Esau, ọmọ mi?” Jakọbu bá dáhùn pé, “Èmi ni.” Nígbà náà ni ó wí pé, “Gbé oúnjẹ náà súnmọ́ mi, kí n jẹ ninu ẹran tí ọmọ mi pa, kí n sì súre fún ọ.” Jakọbu bá gbé oúnjẹ náà súnmọ́ ọn, ó jẹ ẹ́, ó bu ọtí waini fún un, ó sì mu ún. Isaaki baba rẹ̀ bá pè é ó ní, “Súnmọ́ mi, ọmọ mi, kí o sì fi ẹnu kò mí lẹ́nu.” Jakọbu bá súnmọ́ baba rẹ̀, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Baba rẹ̀ gbóòórùn aṣọ rẹ̀, ó sì súre fún un, ó ní, “Òórùn ọmọ mi dàbí òórùn oko tí OLUWA ti bukun. Kí Ọlọrun fún ọ ninu ìrì ọ̀run ati ilẹ̀ tí ó dára ati ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini. Kí àwọn eniyan máa sìn ọ́, kí àwọn orílẹ̀-èdè sì máa tẹríba fún ọ. Ìwọ ni o óo máa ṣe olórí àwọn arakunrin rẹ, àwọn ọmọ ìyá rẹ yóo sì máa tẹríba fún ọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé ọ, òun ni èpè yóo mọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì súre fún ọ, ìre yóo mọ́ ọn.”