Abramu bá dojúbolẹ̀, Ọlọrun tún wí fún un pé, “Majẹmu tí mo bá ọ dá kò yẹ̀ rárá: O óo jẹ́ baba ńlá fún ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè. Orúkọ rẹ kò ní jẹ́ Abramu mọ́, Abrahamu ni o óo máa jẹ́, nítorí mo ti sọ ọ́ di baba ńlá fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè. N óo sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ, n óo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè, ọpọlọpọ ọba ni yóo sì ti ara rẹ jáde.” “N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ láàrin èmi pẹlu rẹ, ati atọmọdọmọ rẹ. Majẹmu náà yóo wà títí ayérayé pé, èmi ni n óo máa jẹ́ Ọlọrun rẹ ati ti atọmọdọmọ rẹ. N óo fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ náà tí o ti jẹ́ àlejò yìí yóo di ìní rẹ títí ayérayé ati ti atọmọdọmọ rẹ, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn!”
Kà JẸNẸSISI 17
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JẸNẸSISI 17:3-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò