Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé, “Ní ti Sarai aya rẹ, má ṣe pè é ní Sarai mọ́, Sara ni orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́. N óo bukun un, n óo sì fún ọ ní ọmọkunrin kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, n óo bukun un, yóo sì di ìyá ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ọpọlọpọ ọba ni yóo wà lára atọmọdọmọ rẹ̀.”
Nígbà náà ni Abrahamu dojúbolẹ̀, ó búsẹ́rìn-ín, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Ọkunrin tí ó ti di ẹni ọgọrun-un (100) ọdún ha tún lè bímọ bí? Sara, tí ó ti di ẹni aadọrun-un ọdún ha tún lè bímọ bí?” Abrahamu bá sọ fún Ọlọrun pé, “Ṣá ti bá mi dá Iṣimaeli yìí sí.”
Ọlọrun dá a lóhùn, pé, “Rárá o, àní, Sara, aya rẹ, yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo sọ ọmọ náà ní Isaaki. N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé fún atọmọdọmọ rẹ̀. Ní ti Iṣimaeli, mo ti gbọ́ ìbéèrè rẹ, wò ó, n óo bukun òun náà, n óo sì fún un ní ọpọlọpọ ọmọ ati ọmọ ọmọ, yóo jẹ́ baba fún àwọn ọba mejila, n óo sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá. Ṣugbọn n óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu Isaaki, tí Sara yóo bí fún ọ ní ìwòyí ọdún tí ń bọ̀.”