Sarai, aya Abramu, kò bímọ fún un. Ṣugbọn ó ní ẹrubinrin ará Ijipti kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hagari. Ní ọjọ́ kan, Sarai pe Abramu, ó sọ fún un pé, “Ṣé o rí i pé OLUWA kò jẹ́ kí n bímọ, nítorí náà bá ẹrubinrin mi yìí lòpọ̀, ó le jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni n óo ti ní ọmọ.” Abramu sì gba ọ̀rọ̀ Sarai aya rẹ̀. Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti dé ilẹ̀ Kenaani ni Sarai, aya rẹ̀ fa Hagari, ará Ijipti, ẹrubinrin rẹ̀ fún un, láti fi ṣe aya. Abramu bá Hagari lòpọ̀, Hagari sì lóyún. Nígbà tí ó rí i pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú tẹmbẹlu Sarai, oluwa rẹ̀. Sarai bá sọ fún Abramu pé, “Ibi tí Hagari ń ṣe sí mi yìí yóo dà lé ọ lórí. Èmi ni mo fa ẹrubinrin mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó rí i pé òun lóyún tán, mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́ lójú rẹ̀. OLUWA ni yóo ṣe ìdájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ.” Ṣugbọn Abramu dá a lóhùn pé, “Ṣebí ìkáwọ́ rẹ ni ẹrubinrin rẹ wà, ṣe é bí ó bá ti wù ọ́.” Sarai bá bẹ̀rẹ̀ sí fòòró ẹ̀mí Hagari, Hagari sì sá kúrò nílé.
Kà JẸNẸSISI 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JẸNẸSISI 16:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò