JẸNẸSISI 15:12-21

JẸNẸSISI 15:12-21 YCE

Nígbà tí oòrùn ń wọ̀ lọ, oorun bẹ̀rẹ̀ sí kun Abramu, ó sì sun àsùnwọra, jìnnìjìnnì mú un, òkùnkùn biribiri sì bò ó mọ́lẹ̀. Nígbà náà ni OLUWA sọ fún un pé, “Mọ̀ dájúdájú pé àwọn ọmọ rẹ yóo lọ gbé ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, wọn yóo di ẹrú níbẹ̀, àwọn ará ibẹ̀ yóo sì mú wọn sìn fún irinwo (400) ọdún. Ṣugbọn n óo mú ìdájọ́ wá sórí orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóo sìn. Àṣẹ̀yìnwá, àṣẹ̀yìnbọ̀, wọn yóo jáde kúrò níbẹ̀ pẹlu ọpọlọpọ dúkìá. Ìwọ náà yóo dàgbà, o óo di arúgbó, ní ọjọ́ àtisùn rẹ, ikú wọ́ọ́rọ́wọ́ ni o óo kú. Atọmọdọmọ rẹ kẹrin ni yóo pada wá síhìn-ín, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò tíì kún ojú òṣùnwọ̀n.” Nígbà tí oòrùn wọ̀, tí ilẹ̀ sì ṣú, kòkò iná tí ó ń rú èéfín ati ìtùfù tí ń jò lálá kan kọjá láàrin àwọn ẹran tí Abramu tò sílẹ̀. Ní ọjọ́ náà ni OLUWA bá a dá majẹmu, ó sọ pé, “Àwọn ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ijipti títí dé odò ńlá nì, àní odò Yufurate, ilẹ̀ àwọn ará Keni, ti àwọn ará Kenisi, ti àwọn ará Kadimoni, ti àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Perisi, ti àwọn ará Refaimu, ti àwọn ará Amori, ti àwọn ará Kenaani, ti àwọn ará Girigaṣi ati ti àwọn ará Jebusi.”