Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, OLUWA bá Abramu sọ̀rọ̀ lójú ìran, ó ní, “Má bẹ̀rù Abramu, n óo dáàbò bò ọ́, èrè rẹ yóo sì pọ̀ pupọ.” Ṣugbọn Abramu dáhùn pé, “OLUWA Ọlọrun, kí ni o óo fún mi, n kò tíì bímọ títí di ìsinsìnyìí! Ṣé Elieseri ará Damasku yìí ni yóo jẹ́ àrólé mi ni? O kò fún mi lọ́mọ, ẹrú tí wọ́n bí ninu ilé mi ni yóo di àrólé mi!” OLUWA bá dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe ọkunrin yìí ni yóo jẹ́ àrólé rẹ, ọmọ bíbí inú rẹ ni yóo jẹ́ àrólé rẹ.” OLUWA bá mú un jáde, ó sì sọ fún un pé, “Wo ojú ọ̀run, kí o ka gbogbo ìràwọ̀ tí ó wà níbẹ̀ bí o bá lè kà wọ́n.” OLUWA bá sọ fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ rẹ yóo ṣe pọ̀ tó.”
Kà JẸNẸSISI 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JẸNẸSISI 15:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò