Ní oṣù keje tí àwọn ọmọ Israẹli ti pada sí ìlú wọn, gbogbo wọn péjọ sí Jerusalẹmu. Jeṣua, ọmọ Josadaki pẹlu àwọn alufaa ẹgbẹ́ rẹ̀ ati Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, pẹlu àwọn ìbátan rẹ̀ tún pẹpẹ Ọlọrun Israẹli kọ́, kí wọ́n baà lè máa rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin Mose, eniyan Ọlọrun. Wọ́n tẹ́ pẹpẹ náà sí ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń bẹ̀rù àwọn eniyan ibẹ̀; wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí rẹ̀ ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́. Wọ́n ṣe àjọ̀dún Àgọ́ Àjọ, wọ́n rú ìwọ̀n ẹbọ sísun tí a ti ṣe ìlànà sílẹ̀ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, wọ́n rú àwọn ẹbọ wọnyi: ẹbọ àtìgbà-dégbà, ẹbọ oṣù titun, gbogbo ẹbọ ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ati ti àwọn tí wọ́n bá fẹ́ rú ẹbọ àtinúwá sí OLUWA. Láti ọjọ́ kinni oṣù keje ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ sísun sí OLUWA bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, wọn kò tíì fi ìpìlẹ̀ tẹmpili lélẹ̀.
Wọ́n fi owó sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń gbẹ́ òkúta ati fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà. Wọ́n fún àwọn ará Sidoni ati àwọn ará Tire ní oúnjẹ, ohun mímu, ati òróró; wọ́n fi ṣe pàṣípààrọ̀ fún igi kedari láti ilẹ̀ Lẹbanoni. Wọ́n ní kí wọ́n kó àwọn igi náà wá sí Jọpa ní etí òkun fún wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Kirusi, ọba Pasia pa. Ní oṣù keji ọdún keji tí wọ́n dé sí ilé Ọlọrun ní Jerusalẹmu ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ati Jeṣua ọmọ Josadaki, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, pẹlu àwọn arakunrin wọn yòókù, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn tí wọ́n ti ìgbèkùn pada sí Jerusalẹmu. Wọ́n yan àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ti tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, láti máa bojútó iṣẹ́ ilé OLUWA. Jeṣua ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu àwọn ìbátan rẹ̀, ati Kadimieli pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Juda ń ṣe alabojuto àwọn tí wọn ń kọ́ ilé Ọlọrun pẹlu àwọn ọmọ Henadadi, ati àwọn Lefi pẹlu àwọn ọmọ wọn ati àwọn ìbátan wọn.
Nígbà tí àwọn mọlémọlé bẹ̀rẹ̀ sí fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀, àwọn alufaa gbé ẹ̀wù wọn wọ̀, wọ́n dúró pẹlu fèrè lọ́wọ́ wọn. Ìdílé Asafu, ẹ̀yà Lefi, ń lu kimbali wọn, wọ́n fí ń yin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ètò tí Dafidi, ọba Israẹli, ti ṣe. Pẹlu orin ìyìn ati ìdúpẹ́ wọ́n ń kọrin sí OLUWA pẹlu ègbè rẹ̀ pé,
“OLUWA ṣeun,
ìfẹ́ rẹ̀ sí Israẹli dúró títí lae.”
Gbogbo àwọn eniyan hó ìhó ìyìn sí OLUWA, nítorí pé wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀. Ṣugbọn ọpọlọpọ àwọn alufaa, àwọn ẹ̀yà Lefi, ati àwọn olórí ìdílé, àwọn àgbàlagbà tí wọ́n gbọ́njú mọ ilé OLUWA ti tẹ́lẹ̀ sọkún, wọ́n kígbe sókè nígbà tí wọ́n rí bí a ti ń fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA náà lélẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mìíràn hó fún ayọ̀. Kò sí ẹni tí ó lè mọ ìyàtọ̀ láàrin ariwo ẹkún ati ti ayọ̀ nítorí pé, gbogbo wọn ń kígbe sókè, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn eniyan sì gbọ́ igbe wọn ní ọ̀nà jíjìn réré.