“Ọba ni yóo ni ilẹ̀ tí ó yí ilẹ̀ mímọ́ náà ká nì ẹ̀gbẹ́ kinni keji, ati àwọn ilẹ̀ tí ó wà ninu ìlú náà, ní ìwọ̀ oòrùn ati ìlà oòrùn, yóo gùn tó ilẹ̀ ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, yóo bẹ̀rẹ̀ ní òpin ìwọ̀ oòrùn yóo sì dé òpin ìlà oòrùn ilẹ̀ náà. Yóo jẹ́ ìpín ti ọba ní Israẹli. Àwọn ọba kò gbọdọ̀ ni àwọn eniyan mi lára mọ́, wọ́n gbọdọ̀ fi ilẹ̀ yòókù sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn.” OLUWA Ọlọrun ní, “Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ̀yin ọba Israẹli, ẹ má hùwà ipá ati ìninilára mọ́, ẹ máa hùwà ẹ̀tọ́ ati òdodo, ẹ má lé àwọn eniyan mi jáde mọ́. “Òṣùnwọ̀n eefa ati ti bati tí ó péye ni kí ẹ máa lò. “Òṣùnwọ̀n eefa ati òṣùnwọ̀n bati náà gbọdọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà, eefa ati bati yín gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n homeri kan. Òṣùnwọ̀n homeri ni ó gbọdọ̀ jẹ́ òṣùnwọ̀n tí ẹ óo máa fi ṣiṣẹ́. “Ogún òṣùnwọ̀n gera ni yóo wà ninu òṣùnwọ̀n ṣekeli kan. Ṣekeli marun-un gbọdọ̀ pé ṣekeli marun-un. Ṣekeli mẹ́wàá sì gbọdọ̀ pé ṣekeli mẹ́wàá; òṣùnwọ̀n mina sì gbọdọ̀ pé aadọta ṣekeli.
Kà ISIKIẸLI 45
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ISIKIẸLI 45:7-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò