OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! Èmi fúnra mi ni n óo wá àwọn aguntan mi, àwárí ni n óo sì wá wọn. Bí olùṣọ́-aguntan tií wá àwọn aguntan rẹ̀ tí ó bá jẹ lọ, bẹ́ẹ̀ ni n óo wá àwọn aguntan mi, n óo sì yọ wọ́n kúrò ninu gbogbo ibi tí wọ́n fọ́nká sí ní ọjọ́ tí ìkùukùu bo ilẹ̀, tí òkùnkùn sì ṣú. N óo mú wọn jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, n óo kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ ayé, n óo sì kó wọn wá sí ilẹ̀ tiwọn. N óo máa bọ́ wọn lórí àwọn òkè Israẹli, lẹ́bàá orísun omi ati gbogbo ibi tí àwọn eniyan ń gbé ní Israẹli. N óo fún wọn ní koríko tí ó dára jẹ, orí òkè Israẹli sì ni wọn óo ti máa jẹ koríko. Níbẹ̀, ninu pápá oko tí ó dára ni wọn óo dùbúlẹ̀ sí; ninu pápá oko tútù, wọn yóo sì máa jẹ lórí àwọn òkè Israẹli. Èmi fúnra mi ni n óo jẹ́ olùṣọ́ àwọn aguntan mi, n óo sì mú wọn dùbúlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun sọ. “N óo wá àwọn tí ó sọnù, n óo sì mú àwọn tí wọ́n ṣáko lọ pada, n óo tọ́jú ọgbẹ́ àwọn tí wọ́n farapa, n óo fún àwọn tí kò lókun lágbára, ṣugbọn àwọn tí wọ́n sanra ati àwọn tí wọ́n lágbára ni n óo parun, nítorí òtítọ́ inú ni n óo fi ṣọ́ àwọn aguntan mi.
Kà ISIKIẸLI 34
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ISIKIẸLI 34:11-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò