Ṣugbọn Mose wí fún OLUWA pé, “OLUWA mi, n kò lè sọ̀rọ̀ dáradára kí o tó bá mi sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni lẹ́yìn tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ̀rọ̀ tán, nítorí pé akólòlò ni mí.” OLUWA dá a lóhùn pé, “Ta ló dá ẹnu eniyan? Ta ni í mú kí eniyan ya odi, tabi kí ó ya adití, tabi kí ó ríran, tabi kí ó ya afọ́jú? Ṣebí èmi OLUWA ni. Nítorí náà, lọ, n óo sì wà pẹlu rẹ, n óo sì máa kọ́ ọ ní ohun tí o óo sọ.” Ṣugbọn Mose tún ní, “OLUWA mi, mo bẹ̀ ọ́, rán ẹlòmíràn.” Inú bí OLUWA sí Mose, ó ní, “Ṣebí Aaroni, ọmọ Lefi, arakunrin rẹ wà níbẹ̀? Mo mọ̀ pé òun lè sọ̀rọ̀ dáradára; ó ń bọ̀ wá pàdé rẹ, nígbà tí ó bá rí ọ, inú rẹ̀ yóo dùn gidigidi. O óo máa bá a sọ̀rọ̀, o óo sì fi ọ̀rọ̀ sí i lẹ́nu. N óo gbàkóso ẹnu rẹ ati ẹnu rẹ̀; n óo sì kọ yín ní ohun tí ẹ óo ṣe. Òun ni yóo máa bá ọ bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀, yóo jẹ́ ẹnu fún ọ, o óo sì dàbí Ọlọrun fún un. Mú ọ̀pá yìí lọ́wọ́, òun ni o óo máa fi ṣe iṣẹ́ ìyanu.”
Kà ẸKISODU 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ẸKISODU 4:10-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò