Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i pé Mose ń pẹ́ jù lórí òkè, wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n tọ Aaroni lọ; wọ́n sọ fún un pé, “Ṣe oriṣa kan fún wa, tí yóo máa ṣáájú wa lọ; nítorí pé, a kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Mose tí ó kó wa wá láti ilẹ̀ Ijipti.” Aaroni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gba gbogbo yẹtí wúrà etí àwọn aya yín jọ, ati ti àwọn ọmọkunrin yín, ati ti àwọn ọmọbinrin yín, kí ẹ sì kó wọn wá.” Gbogbo àwọn eniyan náà bá bọ́ yẹtí wúrà etí wọn jọ, wọ́n kó wọn tọ Aaroni lọ. Aaroni gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn, ó lo irinṣẹ́ àwọn alágbẹ̀dẹ, ó fi wúrà náà da ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kan. Àwọn eniyan náà bá dáhùn pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ọlọrun yín tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìyí.” Nígbà tí Aaroni rí i bẹ́ẹ̀, ó tẹ́ pẹpẹ kan siwaju ère náà, ó sì kéde pé, “Ọ̀la yóo jẹ́ ọjọ́ àjọ fún OLUWA.” Wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, wọ́n rú ẹbọ sísun, wọ́n sì mú ẹbọ alaafia wá, wọ́n bá jókòó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń ṣe àríyá tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn lòpọ̀.
Kà ẸKISODU 32
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ẸKISODU 32:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò