ẸKISODU 20:2-11

ẸKISODU 20:2-11 YCE

“Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ní oko ẹrú tí ẹ wà: “O kò gbọdọ̀ ní ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi. “O kò gbọdọ̀ yá èrekére fún ara rẹ, kì báà ṣe àwòrán ohun tí ó wà ní òkè ọ̀run, tabi ti ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀, tabi ti ohun tí ó wà ninu omi ní abẹ́ ilẹ̀. O kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bọ wọ́n; nítorí Ọlọrun tí í máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ẹ̀ṣẹ̀ baba bi ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ẹkẹrin lára àwọn tí wọ́n kórìíra mi. Ṣugbọn èmi a máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn tí wọ́n fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́. “O kò gbọdọ̀ pe orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ lásán, nítorí pé, èmi OLUWA yóo dá ẹnikẹ́ni tí ó bá pe orúkọ mi lásán lẹ́bi. “Ranti ọjọ́ ìsinmi kí o sì yà á sí mímọ́. Ọjọ́ mẹfa ni kí olukuluku máa fi ṣiṣẹ́, kí ó sì máa fi parí ohun tí ó bá níláti ṣe. Ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí olukuluku níláti yà sọ́tọ̀ fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà; olukuluku yín ati ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, ati ẹrú rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, ati ẹran ọ̀sìn rẹ̀, ati àlejò tí ó wà ninu ilé rẹ̀. Nítorí pé, ọjọ́ mẹfa ni èmi OLUWA fi dá ọ̀run ati ayé, ati òkun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn; mo sì sinmi ní ọjọ́ keje. Nítorí náà ni mo ṣe bukun ọjọ́ ìsinmi náà, tí mo sì yà á sí mímọ́.