“Àwọn òfin ati ìlànà, ati ìdájọ́ tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fún mi láti fi kọ yín nìwọ̀nyí; kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà; kí ẹ lè máa bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, ẹ̀yin ati arọmọdọmọ yín, kí ẹ lè máa tẹ̀lé àwọn ìlànà ati òfin tí mo fun yín lónìí, ní gbogbo ọjọ́ ayé yín, kí ẹ lè pẹ́ láyé. Ẹ gbọ́ nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ máa tẹ̀lé àwọn òfin náà, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pọ̀ sí i, ní ilẹ̀ tí ó dára, tí ó kún fún wàrà ati oyin, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti ṣe ìlérí fun yín. “Ẹ gbọ́ Israẹli: OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA kan ṣoṣo ni. Ẹ gbọdọ̀ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín pẹlu gbogbo ọkàn yín, ati gbogbo ẹ̀mí yín, ati gbogbo agbára yín. Ẹ fi àṣẹ tí mo pa fun yín lónìí sọ́kàn, kí ẹ sì fi kọ́ àwọn ọmọ yín dáradára. Ẹ máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí ẹ bá jókòó ninu ilé yín, ati nígbà tí ẹ bá ń rìn lọ lójú ọ̀nà, ati nígbà tí ẹ bá dùbúlẹ̀, ati nígbà tí ẹ bá dìde. Ẹ so wọ́n mọ́ ọwọ́ yín gẹ́gẹ́ bí àmì, kí ẹ fi ṣe ọ̀já ìgbàjú, kí ó wà ní agbede meji ojú yín. Ẹ kọ wọ́n sí ara òpó ìlẹ̀kùn ilé yín, ati sí ara ẹnu ọ̀nà ìta ilé yín.
Kà DIUTARONOMI 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: DIUTARONOMI 6:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò