“Bí ẹnìkan bá bí ọmọkunrin kan, tí ó jẹ́ aláìgbọràn ati olórí kunkun ọmọ, tí kì í gbọ́, tí kì í sì í gba ti àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n bá a wí títí, ṣugbọn tí kò gbọ́, kí baba ati ìyá rẹ̀ mú un wá siwaju àwọn àgbààgbà ìlú náà, ní ẹnu bodè ìlú tí ó ń gbé, kí wọ́n wí fún àwọn àgbààgbà ìlú náà pé, ‘Ọmọ wa yìí ya olóríkunkun ati aláìgbọràn, kì í gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Oníjẹkújẹ ati onímukúmu sì ni.’ Lẹ́yìn náà kí àwọn ọkunrin ìlú sọ ọ́ ní òkúta pa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó ṣe yọ ibi kúrò láàrin yín; gbogbo Israẹli yóo gbọ́, wọn yóo sì bẹ̀rù.
Kà DIUTARONOMI 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: DIUTARONOMI 21:18-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò