Àwọn ará Kalidea kan wá siwaju ọba, wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn Juu pẹlu ìríra, wọ́n ní, “Kí ọba kí ó pẹ́! Ìwọ ọba ni o pàṣẹ pé nígbàkúùgbà tí ẹnikẹ́ni bá ti gbọ́ ìró fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, kí ó wólẹ̀, kí ó tẹríba fún ère tí o gbé kalẹ̀, ati pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óo sọ ọ́ sinu adágún iná tí ń jó. Àwọn Juu mẹta kan tí ń jẹ́ Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, tí o fi ṣe alákòóso àwọn agbègbè ní ìjọba Babiloni tàpá sí àṣẹ ọba, wọn kò sin ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.”
Inú bí ọba gidigidi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn mẹtẹẹta wá siwaju òun, wọ́n bá kó Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego lọ siwaju ọba. Ó bi wọ́n léèrè pé, “Ṣé nítòótọ́ ni ẹ kò fi orí balẹ̀, kí ẹ sì sin ère wúrà tí mo gbé kalẹ̀? Nisinsinyii, bí ẹ bá ti gbọ́ ìró ipè, fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, tí ẹ bá wólẹ̀, tí ẹ sì sin ère tí mo ti yá, ó dára, ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò wólẹ̀, wọn óo gbe yín sọ sinu adágún iná ìléru. Kò sì sí ọlọrun náà tí ó lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”
Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, kò yẹ kí á máa bá ọ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí. Bí o bá sọ wá sinu iná, Ọlọrun wa tí à ń sìn lè yọ wá ninu adágún iná, ó sì lè gbà wá lọ́wọ́ ìwọ ọba pàápàá. Ṣugbọn bí kò bá tilẹ̀ gbà wá, a fẹ́ kí ọba mọ̀ pé a kò ní fi orí balẹ̀, kí á sin ère wúrà tí ó gbé kalẹ̀.”
Inú bá bí Nebukadinesari gidigidi, ojú rẹ̀ yipada sí Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n dá iná, kí ó gbóná ní ìlọ́po meje ju bíí tií máa ń gbóná tẹ́lẹ̀ lọ. Ó tún pàṣẹ pé kí àwọn akọni ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, kí wọ́n sì sọ wọ́n sinu adágún iná. Wọ́n di àwọn mẹtẹẹta pẹlu agbádá, ati aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀, ati fìlà wọn, ati àwọn aṣọ wọn mìíràn, wọ́n sì sọ wọ́n sí ààrin adágún iná tí ń jó. Nítorí bí àṣẹ ọba ti le tó, ati bí adágún iná náà ti gbóná tó, ahọ́n iná tí ń jó bùlàbùlà jó àwọn tí wọ́n gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sinu rẹ̀ ní àjópa. Nítorí dídì tí wọ́n di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, wọ́n ṣubú lulẹ̀ sí ààrin iná náà.
Lójijì Nebukadinesari ta gìrì, ó sáré dìde, ó sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Ṣebí eniyan mẹta ni a dì, tí a gbé sọ sinu iná?”
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kabiyesi.”
Ó ní, “Ẹ wò ó, eniyan mẹrin ni mo rí yìí, wọ́n wà ní títú sílẹ̀, wọ́n ń rìn káàkiri láàrin iná, iná kò sì jó wọn, Ìrísí ẹni kẹrin dàbí ti ẹ̀dá ọ̀run.”