DANIẸLI 3:26-30

DANIẸLI 3:26-30 YCE

Nebukadinesari ọba bá lọ sí ẹnu ọ̀nà adágún iná náà, ó kígbe pé, “Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, ẹ̀yin iranṣẹ Ọlọrun alààyè, ẹ jáde wá!” Wọ́n bá jáde kúrò ninu iná lẹsẹkẹsẹ. Gbogbo àwọn baálẹ̀ ìgbèríko, àwọn olórí, àwọn gomina, ati àwọn ìgbìmọ̀ ọba, kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí i pé iná kò jó àwọn ọkunrin wọnyi, irun orí wọn kò rùn, ẹ̀wù wọn kò yipada, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tilẹ̀ gbóòórùn iná lára wọn. Nebukadinesari bá dáhùn pé “Ògo ni fún Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e, tí wọn kò ka àṣẹ ọba sí, tí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu, dípò kí wọ́n sin ọlọrun mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọrun wọn. “Nítorí náà, mo pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, tabi orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà tí ó bá sọ̀rọ̀ àbùkù sí Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati ti Abedinego, fífà ni a ó fa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ya ní tapá-titan, a ó sì sọ ilé rẹ̀ di ahoro; nítorí kò sí ọlọrun mìíràn tí ó lè gbani là bẹ́ẹ̀.” Ọba bá gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sí ipò gíga ní ìgbèríko Babiloni.