Nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń ṣe akitiyan tó nítorí yín ati nítorí àwọn tí ó wà ní Laodikia ati nítorí àwọn tí kò mọ̀ mí sójú. Ìdí akitiyan mi ni pé kí Ọlọrun lè mu yín ní ọkàn le, kí ó so yín pọ̀ ninu ìfẹ́ ati ọrọ̀ òye tí ó dájú, kí ẹ sì ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àṣírí Ọlọrun, tíí ṣe Kristi fúnrarẹ̀. Ninu Kristi ni Ọlọrun fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n ati ìmọ̀ pamọ́ sí. Mò ń sọ èyí kí ẹnikẹ́ni má baà fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín jẹ. Nítorí bí n kò tilẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín nípa ti ara, sibẹ mo wà pẹlu yín ninu ẹ̀mí. Mo láyọ̀ nígbà tí mo rí ètò tí ó wà láàrin yín ati bí igbagbọ yín ti dúró ninu Kristi.
Kà KOLOSE 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: KOLOSE 2:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò