ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 8:32-35

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 8:32-35 YCE

Apá ibi tí ó ń kà nìyí: “Bí aguntan tí a mú lọ sí ilé ìpẹran, tí à ń fà níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀, kò fọhùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ya ẹnu rẹ̀. A rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. A kò ṣe ẹ̀tọ́ nípa ọ̀ràn rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò ní lè sọ nípa ìran rẹ̀. Nítorí a pa á run kúrò lórí ilẹ̀ alààyè.” Ìwẹ̀fà náà sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́, ọ̀rọ̀ ta ni wolii Ọlọrun yìí ń sọ, ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ ni tabi ọ̀rọ̀ ẹlòmíràn?” Filipi bá tẹnu bọ ọ̀rọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ láti ibi àkọsílẹ̀ yìí, ó waasu ìyìn rere Jesu fún un.