Àwọn aposteli tí ó wà ní Jerusalẹmu gbọ́ bí àwọn ará Samaria ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Wọ́n bá rán Peteru ati Johanu sí wọn. Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n gbadura fún wọn kí wọ́n lè gba Ẹ̀mí Mímọ́, nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ì tíì bà lé ẹnikẹ́ni ninu wọn. Ìrìbọmi ní orúkọ Oluwa Jesu nìkan ni wọ́n ṣe. Lẹ́yìn tí Peteru ati Johanu ti gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n bá gba Ẹ̀mí Mímọ́. Nígbà tí Simoni rí i pé ọwọ́ tí àwọn aposteli gbé lé wọn ni ó mú kí wọ́n rí Ẹ̀mí gbà, ó fi owó lọ̀ wọ́n. Ó ní, “Ẹ fún mi ní irú àṣẹ yìí kí ẹni tí mo bá gbé ọwọ́ lé, lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.” Ṣugbọn Peteru sọ fún un pé, “Ìwọ ati owó rẹ yóo ṣègbé! O rò pé o lè fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọrun. O kò ní ipa tabi ìpín ninu ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ọkàn rẹ kò tọ́ níwájú Ọlọrun. Nítorí náà, ronupiwada kúrò ninu ohun burúkú yìí, kí o tún bẹ Oluwa kí ó dárí èrò ọkàn rẹ yìí jì ọ́. Nítorí mo wòye pé ẹ̀tanú ti gbà ọ́ lọ́kàn, àtipé aiṣododo ti dè ọ́ lẹ́wọ̀n.” Simoni dá Peteru lóhùn pé, “Ẹ gbadura sí Oluwa fún mi kí ohunkohun tí ẹ wí má ṣẹlẹ̀ sí mi.”
Kà ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 8:14-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò