ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 7:23-43

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 7:23-43 YCE

“Nígbà tí Mose di ẹni ogoji ọdún, ó pinnu pé òun yóo lọ bẹ àwọn ará òun, àwọn ọmọ Israẹli, wò. Ó bá rí ọ̀kan ninu àwọn ará rẹ̀ tí ará Ijipti ń jẹ níyà. Ó bá lọ gbà á sílẹ̀. Ó gbẹ̀san ìyà tí wọ́n ti fi jẹ ẹ́, ó lu ará Ijipti náà pa. Ó rò pé yóo yé àwọn arakunrin òun pé Ọlọrun yóo ti ọwọ́ òun fún wọn ní òmìnira. Ṣugbọn kò yé wọn bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó yọ sí àwọn kan tí wọn ń jà. Ó bá ní kí òun parí ìjà fún wọn. Ó ní, ‘Ẹ̀yin ará, arakunrin ara yín ni ẹ̀ ń ṣe. Kí ló dé tí ẹ̀ ń lu ara yín?’ Ẹni tí ó jẹ̀bi tì í sẹ́yìn, ó ní, ‘Ta ni fi ọ́ ṣe olórí ati onídàájọ́ lórí wa? Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ti ṣe pa ará Ijipti lánàá ni?’ Nígbà tí Mose gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó sálọ. Ó ń lọ gbé ilẹ̀ Midiani. Ó bí ọmọ meji níbẹ̀. “Lẹ́yìn ogoji ọdún, angẹli kán yọ sí i ninu ìgbẹ́ tí ń jóná ní aṣálẹ̀ lẹ́bàá òkè Sinai. Nígbà tí Mose rí ìran náà, ẹnu yà á. Nígbà tí ó súnmọ́ ọn pé kí òun wò ó fínnífínní, ó gbọ́ ohùn Oluwa tí ó sọ pé, ‘Èmi ni Ọlọrun àwọn baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati ti Jakọbu.’ Mose bá bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n. Kò tó ẹni tí í wò ó. Oluwa tún sọ fún un pé, ‘Bọ́ sálúbàtà tí ó wà lẹ́sẹ̀ rẹ, nítorí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí. Mo ti rí gbogbo ìrora tí àwọn eniyan mi ń jẹ ní Ijipti. Mo ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì ṣetán láti yọ wọ́n. Ó yá nisinsinyii. N óo rán ọ lọ sí Ijipti.’ “Mose yìí kan náà, tí wọ́n kọ̀, tí wọ́n sọ fún pé, ‘Ta ni ó fi ọ́ ṣe olórí ati onídàájọ́?’ Òun ni Ọlọrun rán angẹli sí, tí ó farahàn án ninu ìgbẹ́ tí ń jó, láti jẹ́ olórí ati olùdáǹdè. Mose yìí ni aṣaaju wọn, tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì ní ilẹ̀ Ijipti ní Òkun Pupa ati ní ilẹ̀ aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún. Mose yìí ni ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọrun yóo gbé wolii kan bí èmi dìde fun yín láàrin àwọn arakunrin yín.’ Mose náà ni ó bá angẹli sọ̀rọ̀ ní òkè Sinai nígbà tí wọ́n wà ninu àwùjọ ní aṣálẹ̀, tí ó tún bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀. Òun ni ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó fi fún wa. “Ṣugbọn àwọn baba wa kò fẹ́ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́. Wọ́n tì í kúrò lọ́dọ̀ wọn; ọkàn wọn tún pada sí Ijipti. Wọ́n sọ fún Aaroni pé, ‘Ṣe oriṣa fún wa kí á rí ohun máa bọ, kí ó máa tọ́ wa sí ọ̀nà. A kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Mose tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti.’ Wọ́n bá ṣe ère ọmọ mààlúù kan ní àkókò náà, wọ́n rúbọ sí i. Wọ́n bá ń ṣe àríyá lórí ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe. Ọlọrun bá pada lẹ́yìn wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ láti máa sin ìràwọ̀ ojú ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii pé, ‘Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ǹjẹ́ ẹ mú ẹran wá fi rúbọ sí mi fún ogoji ọdún ní aṣálẹ̀? Ṣebí àtíbàbà Moleki ni ẹ gbé rù, ati ìràwọ̀ Refani oriṣa yín, àwọn ère tí ẹ ṣe láti máa foríbalẹ̀ fún? N óo le yín lọ sí ìgbèkùn, ẹ óo kọjá Babiloni.’