ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 7:20-60

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 7:20-60 YCE

Ní àkókò yìí ni a bí Mose. Ó dára lọ́mọ pupọ. Àwọn òbí rẹ̀ tọ́ ọ fún oṣù mẹta ninu ilé baba rẹ̀ Nígbà tí wọ́n sọ ọ́ nù, ni ọmọ Farao, obinrin, bá tọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ti ara rẹ̀. Gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Ijipti ni wọ́n fi kọ́ Mose. Ati ọ̀rọ̀ sísọ, ati iṣẹ́ ṣíṣe kò sí èyí tí kò mọ̀ ọ́n ṣe. “Nígbà tí Mose di ẹni ogoji ọdún, ó pinnu pé òun yóo lọ bẹ àwọn ará òun, àwọn ọmọ Israẹli, wò. Ó bá rí ọ̀kan ninu àwọn ará rẹ̀ tí ará Ijipti ń jẹ níyà. Ó bá lọ gbà á sílẹ̀. Ó gbẹ̀san ìyà tí wọ́n ti fi jẹ ẹ́, ó lu ará Ijipti náà pa. Ó rò pé yóo yé àwọn arakunrin òun pé Ọlọrun yóo ti ọwọ́ òun fún wọn ní òmìnira. Ṣugbọn kò yé wọn bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó yọ sí àwọn kan tí wọn ń jà. Ó bá ní kí òun parí ìjà fún wọn. Ó ní, ‘Ẹ̀yin ará, arakunrin ara yín ni ẹ̀ ń ṣe. Kí ló dé tí ẹ̀ ń lu ara yín?’ Ẹni tí ó jẹ̀bi tì í sẹ́yìn, ó ní, ‘Ta ni fi ọ́ ṣe olórí ati onídàájọ́ lórí wa? Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ti ṣe pa ará Ijipti lánàá ni?’ Nígbà tí Mose gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó sálọ. Ó ń lọ gbé ilẹ̀ Midiani. Ó bí ọmọ meji níbẹ̀. “Lẹ́yìn ogoji ọdún, angẹli kán yọ sí i ninu ìgbẹ́ tí ń jóná ní aṣálẹ̀ lẹ́bàá òkè Sinai. Nígbà tí Mose rí ìran náà, ẹnu yà á. Nígbà tí ó súnmọ́ ọn pé kí òun wò ó fínnífínní, ó gbọ́ ohùn Oluwa tí ó sọ pé, ‘Èmi ni Ọlọrun àwọn baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati ti Jakọbu.’ Mose bá bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n. Kò tó ẹni tí í wò ó. Oluwa tún sọ fún un pé, ‘Bọ́ sálúbàtà tí ó wà lẹ́sẹ̀ rẹ, nítorí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí. Mo ti rí gbogbo ìrora tí àwọn eniyan mi ń jẹ ní Ijipti. Mo ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì ṣetán láti yọ wọ́n. Ó yá nisinsinyii. N óo rán ọ lọ sí Ijipti.’ “Mose yìí kan náà, tí wọ́n kọ̀, tí wọ́n sọ fún pé, ‘Ta ni ó fi ọ́ ṣe olórí ati onídàájọ́?’ Òun ni Ọlọrun rán angẹli sí, tí ó farahàn án ninu ìgbẹ́ tí ń jó, láti jẹ́ olórí ati olùdáǹdè. Mose yìí ni aṣaaju wọn, tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì ní ilẹ̀ Ijipti ní Òkun Pupa ati ní ilẹ̀ aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún. Mose yìí ni ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọrun yóo gbé wolii kan bí èmi dìde fun yín láàrin àwọn arakunrin yín.’ Mose náà ni ó bá angẹli sọ̀rọ̀ ní òkè Sinai nígbà tí wọ́n wà ninu àwùjọ ní aṣálẹ̀, tí ó tún bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀. Òun ni ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó fi fún wa. “Ṣugbọn àwọn baba wa kò fẹ́ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́. Wọ́n tì í kúrò lọ́dọ̀ wọn; ọkàn wọn tún pada sí Ijipti. Wọ́n sọ fún Aaroni pé, ‘Ṣe oriṣa fún wa kí á rí ohun máa bọ, kí ó máa tọ́ wa sí ọ̀nà. A kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Mose tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti.’ Wọ́n bá ṣe ère ọmọ mààlúù kan ní àkókò náà, wọ́n rúbọ sí i. Wọ́n bá ń ṣe àríyá lórí ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe. Ọlọrun bá pada lẹ́yìn wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ láti máa sin ìràwọ̀ ojú ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii pé, ‘Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ǹjẹ́ ẹ mú ẹran wá fi rúbọ sí mi fún ogoji ọdún ní aṣálẹ̀? Ṣebí àtíbàbà Moleki ni ẹ gbé rù, ati ìràwọ̀ Refani oriṣa yín, àwọn ère tí ẹ ṣe láti máa foríbalẹ̀ fún? N óo le yín lọ sí ìgbèkùn, ẹ óo kọjá Babiloni.’ “Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí kan ní aṣálẹ̀. Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀, ó sì pàṣẹ fún un pé kí ó ṣe àgọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí òun ti fihàn án tẹ́lẹ̀. Àwọn baba wa tí wọ́n tẹ̀lé Joṣua gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun lé kúrò níwájú wọn, lẹ́yìn náà wọ́n gbé àgọ́ náà wá. Àgọ́ yìí sì wà pẹlu wa títí di àkókò Dafidi. Dafidi bá ojurere Ọlọrun pàdé; ó wá bèèrè pé kí Ọlọrun jẹ́ kí òun kọ́ ilé fún òun, Ọlọrun Jakọbu. Ṣugbọn Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un. “Bẹ́ẹ̀ ni Ọba tí ó ga jùlọ kì í gbé ilé tí a fi ọwọ́ kọ́. Gẹ́gẹ́ bí wolii nì ti sọ: ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni tìmùtìmù ìtìsẹ̀ mi. Irú ilé wo ni ẹ̀ báà kọ́ fún mi? Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wí. Níbo ni ẹ̀ báà palẹ̀ mọ́ fún mi pé kí n ti máa sinmi? Ṣebí èmi ni mo fọwọ́ mi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi?’ “Ẹ̀yin olóríkunkun, ọlọ́kàn líle, elétí dídi wọnyi! Nígbà gbogbo ni ẹ̀ ń tako Ẹ̀mí Mímọ́. Bí àwọn baba yín ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà rí. Èwo ninu àwọn wolii ni àwọn Baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọ́n pa àwọn tí wọ́n sọtẹ́lẹ̀ pé Ẹni olódodo yóo dé. Ní àkókò yìí ẹ wá dìtẹ̀ sí i, ẹ ṣe ikú pa á. Ẹ̀yin yìí ni ẹ gba òfin Ọlọrun láti ọwọ́ àwọn angẹli, ṣugbọn ẹ kò pa òfin náà mọ́.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ó gún wọn lọ́kàn. Wọ́n bá pòṣé sí i. Ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ gbé Stefanu, ó tẹ ojú mọ́ òkè ọ̀run, ó rí ògo Ọlọrun, ó tún rí Jesu tí ó dúró lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun. Ó bá dáhùn pé, “Ẹ wò ó, mo rí ojú ọ̀run tí ó pínyà. Mo wá rí Ọmọ-Eniyan tí ó dúró lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun.” Ni wọ́n bá kígbe, wọ́n fi ọwọ́ di etí, gbogbo wọ́n rọ́ lù ú; wọ́n fà á jáde lọ sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n bá ń sọ ọ́ ní òkúta. Àwọn ẹlẹ́rìí fi ẹ̀wù wọn lélẹ̀ níwájú ọdọmọkunrin kan tí à ń pè ní Saulu. Bí wọ́n ti ń sọ òkúta lu Stefanu, ó ké pe Jesu Oluwa, ó ní, “Oluwa Jesu, gba ẹ̀mí mi.” Ni ó bá kúnlẹ̀, ó kígbe, ó ní, “Oluwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.” Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó kú.