Nígbà tí ó yá, tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn tí ó ń sọ èdè Giriki ati àwọn tí ó ń sọ èdè Heberu, nítorí wọ́n ń fojú fo àwọn opó àwọn tí ń sọ èdè Giriki dá, nígbà tí wọ́n bá ń pín àwọn nǹkan ní ojoojumọ. Àwọn aposteli mejila bá pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yòókù jọ, wọ́n ní, “Kò yẹ kí á fi iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílẹ̀, kí á máa ṣe ètò oúnjẹ. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ wá ẹni meje láàrin yín, tí wọ́n ní orúkọ rere, tí wọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ ati ọgbọ́n, kí á yàn wọ́n láti mójútó ètò yìí. Àwa ní tiwa, a óo tẹra mọ́ adura gbígbà ati iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ ìyìn rere.” Ọ̀rọ̀ yìí dára lójú gbogbo àwùjọ, wọ́n bá yan Stefanu. Stefanu yìí jẹ́ onigbagbọ tọkàntọkàn, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Wọ́n yan Filipi náà ati Prokoru ati Nikanọ ati Timoni ati Pamena ati Nikolausi ará Antioku tí ó ti gba ẹ̀sìn àwọn Juu. Wọ́n kó wọn wá siwaju àwọn aposteli; wọ́n gbadura, wọ́n bá gbé ọwọ́ lé wọn lórí. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá ń gbilẹ̀. Iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní Jerusalẹmu. Pupọ ninu àwọn alufaa ni wọ́n sì di onigbagbọ. Stefanu ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì ńlá láàrin àwọn eniyan nítorí pé ẹ̀bùn ati agbára Ọlọrun pọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn kan wá láti ilé ìpàdé kan tí à ń pè ní ti àwọn Olómìnira, ti àwọn ará Kurene ati àwọn ará Alẹkisandria; wọ́n tako Stefanu. Àwọn tí wọ́n wá láti Silisia ati láti Esia náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a jiyàn. Ṣugbọn wọn kò lè fèsì sí irú ọgbọ́n ati ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀. Wọ́n bá rú àwọn eniyan nídìí, láti sọ pé, “A gbọ́ nígbà tí ó ń sọ ìsọkúsọ sí Mose ati sí Ọlọrun.” Wọ́n rú àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà ati àwọn amòfin nídìí, ni wọ́n bá mú un, wọ́n fà á lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀. Wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí èké tí wọ́n sọ pé, “Ọkunrin yìí kò yé sọ̀rọ̀ lòdì sí Tẹmpili mímọ́ yìí ati sí òfin Mose. Nítorí a gbọ́ nígbà tí ó sọ pé Jesu ti Nasarẹti yóo wó ilé yìí, yóo yí àwọn àṣà tí Mose fún wa pada.” Gbogbo àwọn tí ó jókòó ní ìgbìmọ̀ tẹjú mọ́ ọn, wọ́n rí ojú rẹ̀ tí ó dàbí ojú angẹli.
Kà ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 6:1-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò