Nígbà tí wọ́n pinnu láti fi wá ranṣẹ sí Itali, wọ́n fi Paulu ati àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn lé balogun ọ̀rún kan tí ó ń jẹ́ Juliọsi lọ́wọ́, ó jẹ́ ọ̀gágun ti ẹgbẹ́ kan tí wọn ń pè ní Ọmọ-ogun Augustu. A bá wọ ọkọ̀ ojú omi kan tí ó ń ti Adiramitu bọ̀ tí ó fẹ́ lọ sí ibi mélòó kan ní Esia. Ọkọ̀ bá ṣí; Arisitakọsi ará Tẹsalonika, ní ilẹ̀ Masedonia, ń bá wa lọ. Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Sidoni. Juliọsi ṣe dáradára sí Paulu. Ó jẹ́ kí ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kí wọ́n fún un ní àwọn nǹkan tí ó nílò. Láti ibẹ̀, a ṣíkọ̀, nítorí pé afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wa, a gba apá Kipru níbi tí afẹ́fẹ́ kò ti fẹ́ pupọ. A la agbami lọ sí apá èbúté Silisia ati Pamfilia títí a fi dé ìlú Mira ní ilẹ̀ Lisia. Níbẹ̀ ni balogun ọ̀rún tí ó ń mú wa lọ ti rí ọkọ̀ Alẹkisandria kan tí ó ń lọ sí Itali. Ni a bá wọ̀ ọ́. Fún ọpọlọpọ ọjọ́, ọkọ̀ kò lè yára rìn. Tipátipá ni a fi dé Kinidusi. Afẹ́fẹ́ ṣe ọwọ́ òdì sí wa. Ni a bá gba ẹ̀gbẹ́ Kirete níbi tí afẹ́fẹ́ kò ti fẹ́ pupọ. A kọjá ibi tí ilẹ̀ gbọọrọ ti wọ ààrin òkun tí wọn ń pè ní Salimone. Tipátipá ni a fi ń lọ lẹ́bàá èbúté títí a fi dé ibìkan tí wọn ń pè ní Èbúté-rere tí kò jìnnà sí ìlú Lasia. A pẹ́ níbẹ̀. Ewu ni bí a bá fẹ́ máa bá ìrìn àjò wa lọ nítorí ọjọ́ ààwẹ̀ ti kọjá. Paulu bá gbà wọ́n níyànjú; ó ní, “Ẹ̀yin ará, mo wòye pé ewu wà ninu ìrìn àjò yìí. Ọpọlọpọ nǹkan ni yóo ṣòfò: ẹrù inú ọkọ̀, ati ọkọ̀ fúnrarẹ̀. Ewu wà fún gbogbo àwa tí a wà ninu ọkọ̀ pàápàá.” Ṣugbọn ọ̀rọ̀ atukọ̀ ati ẹni tó ni ọkọ̀ wọ ọ̀gágun létí ju ohun tí Paulu sọ lọ. Ibi tí wọ́n wà kì í ṣe ibi tí ó dára láti gbé ní ìgbà òtútù. Nítorí náà pupọ ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ rò pé kí àwọn kúrò níbẹ̀, bóyá wọn yóo lè dé Fonike níbi tí wọn yóo lè dúró ní ìgbà òtútù. Èbúté kan ní Kirete ni Fonike; ó kọjú sí ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn gúsù ati ìwọ̀ oòrùn àríwá Kirete. Nígbà tí afẹ́fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ jẹ́jẹ́ láti apá gúsù, wọ́n rò pé ó ti bọ́ sí i fún wọn láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe. Wọ́n bá ṣíkọ̀, wọ́n ń pẹ́ ẹ̀bá Kirete lọ. Kò pẹ́ pupọ ni afẹ́fẹ́ líle kan láti erékùṣù náà bá bì lu ọkọ̀. Wọ́n ń pe afẹ́fẹ́ náà ní èyí tí ó wá láti àríwá ìlà oòrùn. Afẹ́fẹ́ líle yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí taari ọkọ̀. Nítorí pé kò sí ọ̀nà láti fi yí ọkọ̀, kí ó kọjú sí atẹ́gùn yìí, a fi í sílẹ̀ kí afẹ́fẹ́ máa gbé e lọ. A sinmi díẹ̀ nígbà tí a gba gúsù erékùṣù kékeré kan tí ó ń jẹ́ Kauda kọjá. Níbẹ̀, a fi tipátipá so ọkọ̀ kékeré tí ó wà lára ọkọ̀ ńlá wa, kí ó má baà fọ́. Wọ́n bá fà á sinu ọkọ̀ ńlá, wọ́n wá fi okùn so ó mọ́ ara ọkọ̀ ńlá. Ẹ̀rù ń bà wọ́n kí wọn má forí ọkọ̀ sọ ilẹ̀ iyanrìn ní Sitisi, wọ́n bá ta aṣọ-ọkọ̀, kí atẹ́gùn lè máa gbé ọkọ̀ náà lọ. Ní ọjọ́ keji, nígbà tí ìjì túbọ̀ le pupọ, a bá da ẹrù inú ọkọ̀ sinu òkun. Ní ọjọ́ kẹta, ọwọ́ ara wọn ni wọ́n fi da àwọn ohun èèlò inú ọkọ̀ náà sinu òkun. Fún ọpọlọpọ ọjọ́ ni oòrùn kò ràn tí ìràwọ̀ kò sì yọ. Ìjì ńlá ń jà. A bá sọ ìrètí nù pé a tún lè là mọ́.
Kà ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 27
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 27:1-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò