Ó ní “Ẹ̀yin ará mi ati ẹ̀yin baba wa, ẹ fetí sí ẹjọ́ tí mo ní í rò fun yín nisinsinyii.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ tí ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu, wọ́n pa lọ́lọ́. Paulu bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó ní, “Juu ni mí, Tasu ní ilẹ̀ Silisia la gbé bí mi. Ní ìlú yìí ni a gbé tọ́ mi dàgbà. Ilé-ìwé Gamalieli ni mo lọ, ó sì kọ́ mi dáradára nípa Òfin ìbílẹ̀ wa. Mo ní ìtara fún Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti ní lónìí. Mo ṣe inúnibíni sí ọ̀nà ẹ̀sìn yìí. Gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé Jesu ni mò ń lé kiri: ẹni tí mo bá sì bá ninu wọn pípa ni. Èmi a mú wọn, èmi a dè wọ́n, wọn a sì sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, atọkunrin atobinrin wọn. Olórí Alufaa pàápàá lè jẹ́rìí mi, ati gbogbo àwọn àgbààgbà. Ọwọ́ wọn ni mo ti gba ìwé lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arakunrin wa ní Damasku. Mo lọ sibẹ láti de àwọn ẹlẹ́sìn yìí kí n sì mú wọn wá sí Jerusalẹmu láti jẹ wọ́n níyà.
“Bí mo ti ń lọ, tí mo súnmọ́ Damasku, lójijì, ní ọ̀sán gangan, ìmọ́lẹ̀ ńlá kan láti ọ̀run tàn yí mi ká. Mo bá ṣubú lulẹ̀. Mo wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó ń sọ fún mi pé, ‘Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?’ Mo wá dáhùn, mo ní, ‘Ta ni ọ́, Oluwa?’ Ó bá sọ fún mi pé, ‘Èmi ni Jesu ará Nasarẹti, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.’ Àwọn tí wọ́n wà pẹlu mi rí ìmọ́lẹ̀ náà, ṣugbọn wọn kò gbọ́ ohùn ẹni tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀. Mo bá bèèrè pé, ‘Kí ni kí n ṣe Oluwa?’ Oluwa bá dá mi lóhùn pé, ‘Dìde kí o máa lọ sí Damasku. Níbẹ̀ a óo sọ fún ọ gbogbo nǹkan tí a ti ṣètò fún ọ láti ṣe.’ N kò lè ríran mọ́ nítorí ìmọ́lẹ̀ náà mọ́lẹ̀ pupọ. Àwọn ẹni tí ó wà pẹlu mi bá fà mí lọ́wọ́ lọ sí Damasku.
“Lẹ́yìn náà ni ọkunrin kan tí ń jẹ́ Anania dé. Ó jẹ́ olùfọkànsìn nípa ti Òfin Mose; gbogbo àwọn ẹni tí ń gbé Judia ni wọ́n sì jẹ́rìí rere nípa rẹ̀. Ó dúró tì mí, ó ní, ‘Saulu arakunrin, lajú!’ Lẹsẹkẹsẹ ojú mi là, mo bá gbójú sókè wò ó. Ó bá sọ fún mi pé, Ọlọrun àwọn baba wa ni ó yàn mí tẹ́lẹ̀ pé kí n mọ ìfẹ́ rẹ̀, kí n fojú rí iranṣẹ Olódodo rẹ̀, kí n sì gbọ́ ohùn òun pàápàá; kí n lè ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ níwájú gbogbo eniyan nípa ohun tí mo rí, ati ohun tí mo gbọ́. Ó wá bèèrè pé, kí ni mo tún ń fẹ́ nisinsinyii? Ó ní kí n dìde, kí n ṣe ìrìbọmi, kí n wẹ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù, kí n pe orúkọ Oluwa.
“Nígbà tí mo ti pada sí Jerusalẹmu, bí mo ti ń gbadura ninu Tẹmpili, mo rí ìran kan. Mo rí Oluwa tí ó ń sọ fún mi pé, ‘Jáde kúrò ní Jerusalẹmu kíákíá, nítorí wọn kò ní gba ẹ̀rí tí ò ń jẹ́ nípa mi.’ Mo dáhùn, mo ní, ‘Oluwa, àwọn gan-an mọ̀ pé èmi ni mo máa ń sọ àwọn tí ó bá gbà ọ́ gbọ́ sẹ́wọ̀n, tí mo sì máa ń nà wọ́n káàkiri láti ilé ìpàdé kan dé ekeji. Wọ́n mọ̀ pé nígbà tí wọ́n pa Stefanu, ẹlẹ́rìí rẹ, bí mo ti dúró nìyí, tí mò ń kan sáárá sí àwọn tí ó pa á tí mò ń ṣọ́ aṣọ wọn.’ Ṣugbọn Oluwa sọ fún mi pé, ‘Bọ́ sọ́nà, nítorí n óo rán ọ lọ sí ọ̀nà jíjìn, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Juu.’ ”
Àwọn eniyan fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí gbolohun yìí fi jáde. Nígbà tí wọ́n gbọ́ gbolohun yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Ẹ pa irú ẹni bẹ́ẹ̀ rẹ́ kúrò láyé! Kò yẹ kí ó wà láàyè!” Wọ́n bá ń pariwo, wọ́n ń fi aṣọ wọn, wọ́n sì ń da ìyẹ̀pẹ̀ sókè.