ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 20:1-16

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 20:1-16 YCE

Nígbà tí rògbòdìyàn náà kásẹ̀, Paulu ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ó gbà wọ́n níyànjú, ó sì dágbére fún wọn, ó bá lọ sí Masedonia. Bí ó ti ń kọjá ní gbogbo agbègbè náà, bẹ́ẹ̀ ni ó ń gba àwọn eniyan níyànjú pẹlu ọ̀rọ̀ ìwúrí pupọ títí ó fi dé ilẹ̀ Giriki. Ó ṣe oṣù mẹta níbẹ̀. Bí ó ti fẹ́ máa lọ sí Siria, ó rí i pé àwọn Juu ń dìtẹ̀ sí òun, ó bá gba Masedonia pada. Sopata ọmọ Pirusi ará Beria bá a lọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni Arisitakọsi ati Sekundu; ará Tẹsalonika ni wọ́n. Gaiyu ará Dabe ati Timoti náà bá a lọ, ati Tukikọsi ati Tirofimọsi; àwọn jẹ́ ará Esia. Àwọn tí a wí yìí ṣiwaju wa lọ, wọ́n lọ dúró dè wá ní Tiroasi. Àwa náà wá wọkọ̀ ojú omi ní Filipi lẹ́yìn Àjọ̀dún Àìwúkàrà, a bá wọn ní Tiroasi lọ́jọ́ karun-un. Ọjọ́ meje ni a lò níbẹ̀. Ní alẹ́ ọjọ́ Satide, a péjọ láti jẹun; Paulu wá ń bá àwọn onigbagbọ sọ̀rọ̀. Ó ti wà lọ́kàn rẹ̀ pé lọ́jọ́ keji ni òun óo tún gbéra. Nítorí náà ó sọ̀rọ̀ títí dòru. Àtùpà pọ̀ ninu iyàrá òkè níbi tí a péjọ sí. Ọdọmọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Yutiku jókòó lórí fèrèsé. Ó ti sùn lọ níbi tí Paulu gbé ń sọ̀rọ̀ lọ títí. Nígbà tí oorun wọ̀ ọ́ lára, ó ré bọ́ sílẹ̀ láti orí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kẹta. Nígbà tí wọn óo gbé e, ó ti kú. Paulu bá sọ̀kalẹ̀, ó gbá a mú, ó dùbúlẹ̀ lé e lórí. Ó ní, “Ẹ má dààmú, nítorí ẹ̀mí rẹ̀ ṣì wà ninu rẹ̀.” Nígbà tí ó pada sókè, ó gé burẹdi, ó jẹun. Ó wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. Ó bá jáde lọ. Wọ́n mú ọmọ náà lọ sílé láàyè. Èyí sì tù wọ́n ninu lọpọlọpọ. A bọ́ siwaju, a wọkọ̀ ojú omi lọ sí Asọsi. Níbẹ̀ ni a lérò pé Paulu yóo ti wá bá wa tí òun náà yóo sì wọkọ̀. Òun ló ṣe ètò bẹ́ẹ̀ nítorí ó fẹ́ fẹsẹ̀ rìn dé ibẹ̀. Nígbà tí ó bá wa ní Asọsi, ó wọnú ọkọ̀ wa, a bá lọ sí Mitilene. Ní ọjọ́ keji a kúrò níbẹ̀, a dé òdìkejì erékùṣù Kiosi. Ní ọjọ́ kẹta a dé Samosi. Ní ọjọ́ kẹrin a dé Miletu. Nítorí Paulu ti pinnu láti wọkọ̀ kọjá Efesu, kí ó má baà pẹ́ pupọ ní Esia, nítorí ó ń dàníyàn pé bí ó bá ṣeéṣe, òun fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Pẹntikọsti ní Jerusalẹmu.