ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 15:12-21

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 15:12-21 YCE

Ńṣe ni gbogbo àwùjọ dákẹ́ jẹ́ẹ́. Wọ́n wá fetí sílẹ̀ sí ohun tí Banaba ati Paulu níí sọ nípa iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọrun tọwọ́ wọn ṣe láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Lẹ́yìn tí wọ́n ti parí ọ̀rọ̀ tí wọ́n níí sọ, Jakọbu bá fèsì pé, “Ẹ̀yin arakunrin, ẹ fetí sí mi. Simoni ti ròyìn ọ̀nà tí Ọlọrun kọ́kọ́ fi ṣe ìkẹ́ àwọn tí kì í ṣe Juu kí ó lè mú ninu wọn fi ṣe eniyan tirẹ̀. Ọ̀rọ̀ àwọn wolii bá èyí mu, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Lẹ́yìn èyí, n óo tún ilé Dafidi tí ó ti wó kọ́. N óo tún ahoro rẹ̀ mọ, n óo sì gbé e ró. Báyìí ni gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu yóo máa wá Oluwa, ati gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí mo ti pè láti jẹ́ tèmi. Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wí, ó sì jẹ́ kí á mọ ọ̀rọ̀ náà láti ìgbà àtijọ́-tijọ́.’ “Ní tèmi, èrò mi ni pé kí á má tún yọ àwọn tí kì í ṣe Juu tí wọ́n yipada sí Ọlọrun lẹ́nu mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀ kí á kọ ìwé sí wọn pé kí wọ́n takété sí ohunkohun tí ó bá ti di àìmọ́ nítorí pé a ti fi rúbọ sí oriṣa; kí wọn má ṣe àgbèrè, kí wọn má jẹ ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa, kí wọn má sì jẹ ẹ̀jẹ̀. Nítorí láti ìgbà àtijọ́ ni wọ́n ti ń ké òkìkí Mose láti ìlú dé ìlú tí wọn sì ń ka ìwé rẹ̀ ninu gbogbo ilé ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.”