“Nítorí náà, ẹ̀tọ́ ni kí á yan ẹnìkan ninu àwọn tí ó ti wà pẹlu wa ní gbogbo àkókò tí Jesu Oluwa ti ń wọlé, tí ó ń jáde pẹlu wa, láti àkókò tí Johanu ti ń ṣe ìrìbọmi títí di ọjọ́ tí a fi mú Jesu kúrò lọ́dọ̀ wa, kí olúwarẹ̀ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí ajinde Jesu, kí ó sì di ọ̀kan ninu wa.” Wọ́n bá gbé ẹni meji siwaju: Josẹfu tí à ń pè ní Basaba, tí ó tún ń jẹ́ Jusitu, ati Matiasi. Wọ́n gbadura pé, “Ìwọ Oluwa, Olùmọ̀ràn gbogbo eniyan, fi ẹni tí o bá yàn ninu àwọn mejeeji yìí hàn, kí ó lè gba iṣẹ́ yìí ati ipò aposteli tí Judasi fi sílẹ̀ láti lọ sí ààyè tirẹ̀.” Wọ́n bá ṣẹ́ gègé. Gègé bá mú Matiasi. Ó bá di ọ̀kan ninu àwọn aposteli mọkanla.
Kà ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 1:21-26
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò