KỌRINTI KEJI 2:3-13

KỌRINTI KEJI 2:3-13 YCE

Ìdí tí mo fi kọ ìwé tí mo kọ si yín nìyí, nítorí n kò fẹ́ wá kí n tún ní ìbànújẹ́ láti ọ̀dọ̀ ẹ̀yin tí ó yẹ kí ẹ fún mi láyọ̀. Ó dá mi lójú pé bí mo bá ń yọ̀, inú gbogbo yín ni yóo máa dùn. Nítorí pẹlu ọpọlọpọ ìdààmú ati ọkàn wúwo ni mo fi kọ ọ́, kì í ṣe pé kí ó lè bà yín lọ́kàn jẹ́ ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé ìfẹ́ tí mo ní si yín pọ̀ pupọ. Ní ti ẹni tí ó dá ìbànújẹ́ yìí sílẹ̀, èmi kọ́ ni ó bà ninu jẹ́ rárá. Láì tan ọ̀rọ̀ náà lọ títí, bí ó ti wù kí ó mọ, gbogbo yín ni ó bà ninu jẹ́. Ìyà tí ọpọlọpọ ninu yín ti fi jẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti tó. Kí ẹ wá dáríjì í. Kí ẹ fún un ní ìwúrí. Bí ìbànújẹ́ bá tún pọ̀ lápọ̀jù kí ó má baà wó irú ẹni bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀. Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ jẹ́ kí ó mọ̀ pé ẹ fẹ́ràn òun. Ìdí tí mo fi kọ ìwé sí yín ni láti fi dán yín wò, kí n lè mọ̀ bí ẹ bá ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu ninu ohun gbogbo. Bí ẹ bá dáríjì ẹnikẹ́ni, èmi náà dáríjì í. Nítorí tí mo bá ti dáríjì eniyan, (bí nǹkankan bá fi ìgbà kan wà tí mo fi níláti dáríjì ẹnikẹ́ni), mo ṣe é nítorí tiyín níwájú Kristi. Nítorí a kò gbọdọ̀ gba Èṣù láyè láti lò wá, nítorí a kò ṣàì mọ ète rẹ̀. Nígbà tí mo dé Tiroasi láti waasu ìyìn rere Kristi, Oluwa ṣínà fún mi láti ṣiṣẹ́. Ṣugbọn ọkàn mi kò balẹ̀ nígbà tí n kò rí Titu arakunrin mi níbẹ̀. Mo bá dágbére fún àwọn eniyan níbẹ̀, mo lọ sí Masedonia.