Gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, ọ̀rọ̀ wa pẹlu yín ti kúrò ní “bẹ́ẹ̀ ni” ati “bẹ́ẹ̀ kọ́.” Nítorí Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun, tí èmi, Silifanu ati Timoti, ń waasu rẹ̀ fun yín, kì í ṣe “bẹ́ẹ̀ ni” ati “bẹ́ẹ̀ kọ́”. Ṣugbọn “bẹ́ẹ̀ ni” ni tirẹ̀. Nítorí gbogbo ìlérí Ọlọrun di “bẹ́ẹ̀ ni” ninu rẹ̀. Ìdí tí a fi ń ṣe “Amin” ní orúkọ rẹ̀ nìyí, nígbà tí a bá ń fi ògo fún Ọlọrun. Ọlọrun ni ó fún àwa ati ẹ̀yin ní ìdánilójú pé a wà ninu Kristi, òun ni ó ti fi òróró yàn wá. Ó ti fi èdìdì rẹ̀ sí wa lára, ó tún fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe onídùúró sí ọkàn wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí yóo tún fún wa.
Kà KỌRINTI KEJI 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: KỌRINTI KEJI 1:18-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò