Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọrun, ati Timoti, arakunrin wa, ni à ń kọ ìwé yìí sí Ìjọ Ọlọrun tí ó wà ní Kọrinti ati sí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun tí ó wà ní Akaya.
Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu yín.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba aláàánú ati Ọlọrun orísun ìtùnú, ẹni tí ó ń fún wa ní ìwúrí ninu gbogbo ìpọ́njú tí à ń rí, kí àwa náà lè fi ìwúrí fún àwọn tí ó wà ninu oríṣìíríṣìí ìpọ́njú nípa ìwúrí tí àwa fúnra wa ti níláti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti ní ìpín ninu ọpọlọpọ ìyà Kristi, bẹ́ẹ̀ náà ni a ní ọpọlọpọ ìwúrí nípasẹ̀ Kristi. Ṣugbọn bí a bá wà ninu ìpọ́njú, fún ìwúrí ati ìgbàlà yín ni. Bí a bá ní ìwúrí, ẹ̀yin náà yóo ní ìwúrí; ìwúrí yìí yóo sì kọ yín ní sùúrù nígbà tí ẹ bá ń jẹ irú ìyà tí àwa náà ń jẹ. Ìrètí wa lórí yín sì ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, nítorí tí a mọ̀ pé bí a ti jọ ń jẹ irú ìyà kan náà, bẹ́ẹ̀ náà ni a jọ ní irú ìwúrí kan náà.
Ẹ̀yin ará, a kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nípa ìpọ́njú tí ó tayọ agbára wa tí a ní ní Esia, Ìdààmú náà wọ̀ wá lọ́rùn tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀mí wa fi fẹ́rẹ̀ bọ́. A ṣe bí wọ́n tí dá wa lẹ́bi ikú ni. Kí á má baà gbẹ́kẹ̀lé ara wa, bíkòṣe Ọlọrun, ni ọ̀rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Nítorí Ọlọrun níí jí òkú dìde. Ọlọrun ni ó yọ wá ninu ewu ńlá náà, òun ni yóo sì máa yọ wá. Òun ni a ní ìrètí ninu rẹ̀; yóo sì tún máa yọ wá, bí ẹ bá ń fi adura yín ràn wá lọ́wọ́. Nígbà náà ni ọpọlọpọ eniyan yóo ṣọpẹ́ nítorí ọpọlọpọ oore tí Ọlọrun ṣe fún wa.
Nǹkankan wà tí a lè fi ṣe ìgbéraga, ẹ̀rí-ọkàn wa sì jẹ́rìí sí i pé pẹlu ọkàn kan ati inú kan níwájú Ọlọrun ni a fi ń bá gbogbo eniyan lò, pàápàá jùlọ ẹ̀yin gan-an. Kì í ṣe ọgbọ́n eniyan bíkòṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Kò sí ohunkohun tí a kọ si yín tí ẹ kò lè kà kí ó ye yín. Mo sì ní ìrètí pé yóo ye yín jálẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé ẹ kò ì tíì mọ̀ wá dáradára, ẹ óo rí i pé a óo jẹ́ ohun ìṣògo fun yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà yóo ti jẹ́ fún wa ní ọjọ́ tí Oluwa wa, Jesu, bá dé. Nítorí ó dá mi lójú bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe fẹ́ kọ́kọ́ wá sọ́dọ̀ yín, kí ayọ̀ yín lè di ìlọ́po meji. Ǹ bá gba ọ̀dọ̀ yín lọ sí Masedonia, ǹ bá sì tún gba ọ̀dọ̀ yín lábọ̀. Ǹ bá wá ṣe ètò láti wá ìrànlọ́wọ́ fún ìrìn àjò mi sí Judia. Ohun tí mo ní lọ́kàn nìyí. Ǹjẹ́ kò ní ìdí tí mo fi yí ètò yìí pada? Àbí ẹ rò pé nígbà tí mò ń ṣe ètò, mò ń ṣe é bí ẹni tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni, tí ó fi jẹ́ pé ẹnu kan náà tí mo fi pe “bẹ́ẹ̀ ni” ni n óo tún fi pe “bẹ́ẹ̀ kọ́?” Gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, ọ̀rọ̀ wa pẹlu yín ti kúrò ní “bẹ́ẹ̀ ni” ati “bẹ́ẹ̀ kọ́.” Nítorí Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun, tí èmi, Silifanu ati Timoti, ń waasu rẹ̀ fun yín, kì í ṣe “bẹ́ẹ̀ ni” ati “bẹ́ẹ̀ kọ́”. Ṣugbọn “bẹ́ẹ̀ ni” ni tirẹ̀. Nítorí gbogbo ìlérí Ọlọrun di “bẹ́ẹ̀ ni” ninu rẹ̀. Ìdí tí a fi ń ṣe “Amin” ní orúkọ rẹ̀ nìyí, nígbà tí a bá ń fi ògo fún Ọlọrun. Ọlọrun ni ó fún àwa ati ẹ̀yin ní ìdánilójú pé a wà ninu Kristi, òun ni ó ti fi òróró yàn wá. Ó ti fi èdìdì rẹ̀ sí wa lára, ó tún fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe onídùúró sí ọkàn wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí yóo tún fún wa.
Mo fi Ọlọrun jẹ́rìí ohun tí n óo sọ yìí. Mo sì fi ẹ̀mí mi búra! Ìdí tí n kò fi wá sí Kọrinti mọ́ ni pé n kò fẹ́ yọ yín lẹ́nu. Kì í ṣe pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ fi agbára ti igbagbọ bọ̀ yín lọ́rùn ni, nítorí ẹ ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu igbagbọ. Ṣugbọn a jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹlu yín ni, kí ẹ lè ní ayọ̀.