Dafidi dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó fi ẹnìkan ṣọ́ agbo ẹran rẹ̀, ó mú oúnjẹ náà, ó sì lọ gẹ́gẹ́ bí Jese ti pàṣẹ fún un. Ó dé ibùdó ogun ní àkókò tí àwọn ọmọ ogun ń lọ sójú ogun, wọ́n ń hó ìhó ogun. Àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti Filistini dúró ní ipò wọn, wọ́n ń wo ara wọn. Dafidi fún olùtọ́jú ẹrù àwọn ọmọ ogun ní oúnjẹ tí ó gbé lọ, ó sì sáré tọ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ sójú ogun láti kí wọn. Bí ó ti ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Goliati wá láti pe àwọn ọmọ ogun Israẹli níjà. Ó sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń sọ ọ́; Dafidi sì gbọ́. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Israẹli rí Goliati, ẹ̀rù bà wọ́n; wọ́n sì sá lọ. Wọ́n ní, “Ẹ wo ọkunrin yìí, ẹ gbọ́ bí ó ti ń pe Israẹli níjà? Ọba sì ti sọ pé ẹni tí ó bá lè pa á yóo gba ẹ̀bùn lọpọlọpọ. Òun yóo sì fi ọmọbinrin òun fún olúwarẹ̀, ilé baba rẹ̀ yóo sì di òmìnira ní ilẹ̀ Israẹli: kò ní san owó orí mọ́.”
Dafidi bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọkunrin náà pé, “Kí ni ọba ṣe ìlérí pé òun ó fún ẹni tí ó bá pa Filistini yìí, tí ó sì mú ẹ̀gàn kúrò lára Israẹli? Ta ni aláìkọlà Filistini yìí tí ń pẹ̀gàn àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè?” Àwọn ọkunrin náà sì sọ ohun tí ọba sọ pé òun yóo ṣe fún ẹni tí ó bá pa ọkunrin náà fún Dafidi.
Nígbà tí Eliabu, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àgbà gbọ́ tí ó ń bá àwọn ọkunrin náà sọ̀rọ̀, ó bínú sí Dafidi, ó ní, “Kí ni ìwọ ń wá níbí? Ta ni ó ń tọ́jú àwọn aguntan rẹ ninu pápá? Ìwọ onigbeeraga ati ọlọ́kàn líle yìí, nítorí kí o lè wo ogun ni o ṣe wá síbí.”
Dafidi sì dáhùn pé, “Kí ni mo ṣe nisinsinyii? Ṣebí ọ̀rọ̀ lásán ni mò ń sọ.” Dafidi yipada kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn, ó tún bèèrè ìbéèrè kan náà. Àwọn ọkunrin náà sì fún un ní èsì bíi ti iṣaaju.
Àwọn ọmọ ogun náà sọ ọ̀rọ̀ tí Dafidi sọ níwájú Saulu, Saulu bá ranṣẹ pè é. Dafidi sọ fún Saulu pé, “Ẹ má bẹ̀rù ọkunrin yìí; èmi, iranṣẹ rẹ óo lọ bá a jà.”
Saulu bá sọ fún Dafidi pé, “O kò lè bá Filistini yìí jà, nítorí pé ọmọde ni ọ́, òun sì ti jẹ́ jagunjagun láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.”
Dafidi dáhùn pé, “Ìgbàkúùgbà tí èmi iranṣẹ rẹ bá ń ṣọ́ agbo aguntan baba mi, tí kinniun tabi ẹranko beari bá gbé ọ̀kan ninu aguntan náà, n óo tẹ̀lé e lọ, n óo lù ú, n óo sì gba aguntan náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Bí ó bá sì kọjú ìjà sí mi, n óo di ọ̀fun rẹ̀ mú, n óo sì pa á. Èmi iranṣẹ rẹ yìí ti pa àwọn kinniun ati àwọn ẹranko beari rí, aláìkọlà Filistini yìí yóo sì dàbí ọ̀kan ninu wọn, nítorí pé, ó ti pe àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè níjà. OLUWA tí ó gbà mí lọ́wọ́ kinniun ati beari yóo gbà mí lọ́wọ́ Filistini yìí.”
Saulu bá sọ fún Dafidi pé, “Máa lọ, OLUWA yóo wà pẹlu rẹ.” Saulu gbé ihamọra ogun rẹ̀ wọ Dafidi, ó fi àṣíborí idẹ kan dé e lórí, ó sì gbé ẹ̀wù tí a fi irin pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe wọ̀ ọ́. Dafidi di idà Saulu mọ́ ihamọra náà, ó sì gbìyànjú láti rìn, ṣugbọn kò lè rìn nítorí pé kò wọ ihamọra ogun rí. Dafidi sọ fún Saulu pé, “N kò lè lo ihamọra yìí, nítorí pé n kò wọ̀ ọ́ rí.” Dafidi bá tú wọn kúrò lára rẹ̀. Ó mú ọ̀pá darandaran rẹ̀, ó ṣa òkúta marun-un tí ń dán ninu odò, ó kó wọn sinu àpò rẹ̀, ó mú kànnàkànnà rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì lọ bá Filistini náà.