Bẹ́ẹ̀ ni Ahabu ọba ṣe kú; wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ sí Samaria, wọ́n sì sin ín sibẹ. Wọ́n lọ fọ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ní adágún Samaria, àwọn ajá lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, àwọn aṣẹ́wó sì lọ wẹ̀ ninu adágún náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀ pé yóo rí. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Ahabu ọba ṣe, ati àkọsílẹ̀ bí ó ṣe fi eyín erin ṣe iṣẹ́ ọnà sí ààfin rẹ̀, ati ti gbogbo ìlú tí ó tẹ̀dó, wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
Kà ÀWỌN ỌBA KINNI 22
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÀWỌN ỌBA KINNI 22:37-39
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò