ÀWỌN ỌBA KINNI 18:25-39

ÀWỌN ỌBA KINNI 18:25-39 YCE

Elija bá sọ fún àwọn wolii Baali pé, “Ẹ̀yin ni ẹ pọ̀, ẹ̀yin ẹ kọ́kọ́ mú akọ mààlúù kan, kí ẹ tọ́jú rẹ̀. Ẹ gbadura sí oriṣa yín ṣugbọn ẹ má fi iná sí igi ẹbọ yín.” Wọ́n mú akọ mààlúù tí wọ́n fún wọn, wọ́n pa á, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe oriṣa Baali láti àárọ̀ títí di ọ̀sán. Wọ́n ń wí pé, “Baali, dá wa lóhùn!” Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò fọhùn. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jó yípo pẹpẹ tí wọ́n kọ́. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò dá wọn lóhùn. Nígbà tí ó di ọ̀sán, Elija bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ pé, “Ẹ kígbe sókè, nítorí pé Ọlọrun ṣá ni. Bóyá ó ronú lọ ni, bóyá ó sì wọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ lọ ni; tabi ó lè jẹ́ pé ó lọ sí ìrìn àjò ni. Bóyá ó sùn ni, ẹ sì níláti jí i.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe sókè, wọ́n ń fi idà ati ọ̀kọ̀ ya ara wọn lára, gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, títí tí ẹ̀jẹ̀ fi bò wọ́n. Nígbà tí ọ̀sán pọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, wọ́n ń sáré kiri bíi wèrè, títí tí ó fi di àkókò ìrúbọ ọ̀sán, ṣugbọn Baali kò dá wọn lóhùn rárá. Kò tilẹ̀ fọhùn. Nígbà tó yá, Elija wí fún gbogbo àwọn eniyan náà pé, “Ẹ súnmọ́ mi níhìn-ín.” Gbogbo wọn súnmọ́ ọn, wọ́n sì yí i ká. Ó bá tún pẹpẹ OLUWA tí ó ti wó ṣe. Ó kó òkúta mejila jọ, òkúta kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Jakọbu, ẹni tí OLUWA sọ fún pé, “Israẹli ni orúkọ rẹ yóo máa jẹ́.” Ó fi òkúta mejeejila náà kọ́ pẹpẹ ní orúkọ OLUWA. Ó gbẹ́ kòtò kan yí pẹpẹ náà ká, kòtò náà tóbi tó láti gba òṣùnwọ̀n irúgbìn meji (nǹkan bíi lita mẹrinla). Lẹ́yìn náà, ó to igi sórí pẹpẹ, ó gé akọ mààlúù náà sí wẹ́wẹ́, ó sì tò wọ́n sórí igi. Ó ní kí wọ́n pọn ẹ̀kún ìkòkò omi ńlá mẹrin, kí wọ́n dà á sórí ẹbọ ati igi náà, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní kí wọ́n tún da mẹrin mìíràn, wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní kí wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀ lẹẹkẹta, wọ́n sì tún ṣe bẹ́ẹ̀. Omi náà ṣàn sílẹ̀ yí pẹpẹ ká, ó sì kún kòtò tí wọ́n gbẹ́ yípo. Nígbà tí ó di àkókò ìrúbọ ìrọ̀lẹ́, Elija súnmọ́ ibi pẹpẹ náà, ó sì gbadura pé, “OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Israẹli, fi hàn lónìí pé ìwọ ni Ọlọrun Israẹli, ati pé iranṣẹ rẹ ni mí, ati pé gbogbo ohun tí mò ń ṣe yìí, pẹlu àṣẹ rẹ ni. Dá mi lóhùn, OLUWA, dá mi lóhùn; kí àwọn eniyan wọnyi lè mọ̀ pé ìwọ OLUWA ni Ọlọrun, ati pé ìwọ ni o fẹ́ yí ọkàn wọn pada sọ́dọ̀ ara rẹ.” OLUWA bá sọ iná sílẹ̀, iná náà sì jó ẹbọ náà ati igi, ati òkúta. Ó jó gbogbo ilẹ̀ ibẹ̀, ó sì lá gbogbo omi tí ó wà ninu kòtò. Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n wí pé, “OLUWA ni Ọlọrun! OLUWA ni Ọlọrun!”