Ojú kò lè wí fún ọwọ́ pé, “N kò nílò rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni orí kò lè wí fún ẹsẹ̀ pé, “N kò nílò yín.” Kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn ẹ̀yà ara tí kò lágbára jẹ́ àwọn tí a kò lè ṣe aláìní. Àwọn ẹ̀yà mìíràn tí a rò pé wọn kò dùn ún wò ni à ń dá lọ́lá jù. Àwọn ẹ̀yà ara tí kò dùn ún wò ni à ń yẹ́ sí jùlọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹ̀yà ara tí ó dùn ún wò kò nílò ọ̀ṣọ́ lọ títí. Ọlọrun ti ṣe ètò àwọn ẹ̀yà ara ní ọ̀nà tí ó fi fi ọlá fún àwọn ẹ̀yà tí kò dùn ún wò, kí ó má baà sí ìyapa ninu ara, ṣugbọn kí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara lè máa ṣe aájò kan náà fún ara wọn. Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jẹ ìrora, gbogbo àwọn ẹ̀yà yòókù níí máa bá a jẹ ìrora. Bí ara bá tu ẹ̀yà kan, gbogbo àwọn ẹ̀yà yòókù ni yóo máa bá a yọ̀.
Kà KỌRINTI KINNI 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: KỌRINTI KINNI 12:21-26
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò