1
Romu 14:17-18
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Nítorí ìjọba ọ̀run kì í ṣe jíjẹ àti mímu, bí kò ṣe nípa ti òdodo, àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Ẹ̀mí Mímọ́, nítorí ẹni tí ó bá sin Kristi nínú nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ní ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Romu 14:17-18
2
Romu 14:8
Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa; bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa. Nítorí náà, bí a wà láààyè, tàbí bí a kú, ti Olúwa ni àwa i ṣe.
Ṣàwárí Romu 14:8
3
Romu 14:19
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ṣa gbogbo ipá wa láti máa lépa àlàáfíà, àti ohun tí àwa yóò fi gbé ara wa ró.
Ṣàwárí Romu 14:19
4
Romu 14:13
Nítorí náà, ẹ má ṣe tún jẹ́ kí a máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má ṣe fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arákùnrin tàbí arábìnrin yín.
Ṣàwárí Romu 14:13
5
Romu 14:11-12
A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: “ ‘Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè,’ ni Olúwa wí, ‘gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi; gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run.’ ” Ǹjẹ́ nítorí náà, olúkúlùkù wa ni yóò jíyìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.
Ṣàwárí Romu 14:11-12
6
Romu 14:1
Ẹ gba ẹni tí ó bá ṣe àìlera ní ìgbàgbọ́ mọ́ra, kí ẹ má ṣe tọpinpin ìṣeyèméjì rẹ̀.
Ṣàwárí Romu 14:1
7
Romu 14:4
Ta ni ìwọ láti dá ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Lójú olúwa tirẹ̀ ni òun dúró, tàbí ṣubú. Òun yóò sì dúró nítorí Ọlọ́run ní agbára láti mú kí òun dúró.
Ṣàwárí Romu 14:4
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò