1
Saamu 40:1-2
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de OLúWA; ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi. Ó fà mí yọ gòkè láti inú ihò ìparun, láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta, ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Saamu 40:1-2
2
Saamu 40:3
Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu, àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa. Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù, wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé OLúWA.
Ṣàwárí Saamu 40:3
3
Saamu 40:4
Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó fi OLúWA ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga, tàbí àwọn tí ó yapa lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.
Ṣàwárí Saamu 40:4
4
Saamu 40:8
Mo ní inú dídùn láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi; Òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”
Ṣàwárí Saamu 40:8
5
Saamu 40:11
Ìwọ má ṣe, fa àánú rẹ tí ó rọ́nú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; OLúWA jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ kí ó máa pa mi mọ́ títí ayérayé.
Ṣàwárí Saamu 40:11
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò