1
Òwe 16:3
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé OLúWA lọ́wọ́ Èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Òwe 16:3
2
Òwe 16:9
Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀ ṣùgbọ́n OLúWA ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.
Ṣàwárí Òwe 16:9
3
Òwe 16:24
Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.
Ṣàwárí Òwe 16:24
4
Òwe 16:1
Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ OLúWA ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.
Ṣàwárí Òwe 16:1
5
Òwe 16:32
Ó sàn láti jẹ́ onísùúrù ju ajagun ènìyàn lọ, ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun ṣẹ́gun ìlú lọ.
Ṣàwárí Òwe 16:32
6
Òwe 16:18
Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun, agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú.
Ṣàwárí Òwe 16:18
7
Òwe 16:2
Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dàbí i pé ó dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n OLúWA ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn.
Ṣàwárí Òwe 16:2
8
Òwe 16:20
Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ìre, ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLúWA.
Ṣàwárí Òwe 16:20
9
Òwe 16:8
Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ.
Ṣàwárí Òwe 16:8
10
Òwe 16:25
Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.
Ṣàwárí Òwe 16:25
11
Òwe 16:28
Aláyídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀ olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ní yà.
Ṣàwárí Òwe 16:28
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò